8 Méjìméjì ni àwọn ẹran tí ó jẹ́ mímọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà,
9 akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Nóà sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà.
10 Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé.
11 Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kéjì, tí Nóà pé ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún, ni gbogbo ìṣun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì sí sílẹ̀.
12 Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.
13 Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan-an ni Nóà àti Ṣémù, Ámù àti Jáfétì pẹ̀lú aya Nóà àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀.
14 Wọn mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn.