1 Ọlọ́run sì rántí Nóà àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà.
2 Gbogbo ìṣun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró.
3 Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yín àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà.
4 Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ ṣórí òkè Árárátì.
5 Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹ́wàá, orí àwọn òkè sì farahàn.
6 Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Nóà sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀.
7 Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti ṣẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀.