1 Jí, Sioni, jí!Gbé agbára rẹ wọ̀ bí aṣọ,gbé ẹwà rẹ wọ̀ bí ẹ̀wù,ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́;nítorí àwọn aláìkọlà ati aláìmọ́, kò ní wọ inú rẹ mọ́.
2 Dìde, gbọnranù kúrò ninu erùpẹ̀,ìwọ Jerusalẹmu tí ó wà ninu ìdè.Tú okùn tí a dè mọ́ ọ lọ́rùn kúrò,ìwọ Sioni tí ó wà ninu ìdè.
3 Nítorí OLUWA ní, “Ọ̀fẹ́ ni a mu yín lẹ́rú, ọ̀fẹ́ náà sì ni a óo rà yín pada.
4 Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn eniyan mi lọ ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà, àwọn ará Asiria pọ́n wọn lójú láì nídìí.
5 Ṣugbọn nisinsinyii, kí ni mo rí yìí? Wọ́n mú àwọn eniyan mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn alákòóso wọn ń pẹ̀gàn, orúkọ mi wá di nǹkan yẹ̀yẹ́?
6 Nítorí náà àwọn eniyan mi yóo mọ orúkọ mi, wọn óo sì mọ̀ ní ọjọ́ náà pé, èmi tí mò ń sọ̀rọ̀, èmi náà nìyí.”