10 Ẹ lè máa gbé láàrin wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrin wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.”
11 Ṣékémù sì wí fún baba àti arákùnrin Dínà pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojú rere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà.
12 Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san-án, kí ẹ sáà jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya.”
13 Àwọn arákùnrin Dínà sì fi ẹ̀tàn dá Ṣékémù àti Ámórì bàbá rẹ̀ lóhùn nítorí tí ó ti ba ògo Dínà arábìnrin wọn jẹ́.
14 Wọ́n wí fún wọn pé, “Àwa kò le ṣe nǹkan yìí láti fi arábìnrin wa fún aláìkọlà, nítorí àbùkù ni èyí yóò jẹ́ fún wa.
15 Àwa yóò fara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà.
16 Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín. A ó máa gbé láàrin yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín.