13 Àwọn arákùnrin Dínà sì fi ẹ̀tàn dá Ṣékémù àti Ámórì bàbá rẹ̀ lóhùn nítorí tí ó ti ba ògo Dínà arábìnrin wọn jẹ́.
14 Wọ́n wí fún wọn pé, “Àwa kò le ṣe nǹkan yìí láti fi arábìnrin wa fún aláìkọlà, nítorí àbùkù ni èyí yóò jẹ́ fún wa.
15 Àwa yóò fara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà.
16 Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín. A ó máa gbé láàrin yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín.
17 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti kọlà, àwa yóò mú arábìnrin wa, á ó sì máa lọ.”
18 Àbá náà sì dùn mọ́ Ámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀.
19 Ọ̀dọ́mọkùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni iyì jùlọ ní ilé bàbá rẹ̀, kò jáfara láti ṣe ohun tí wọ́n wí. Nítorí tí ó fẹ́ràn ọmọbìnrin Jákọ́bù.