2 Ọlọ́run sì bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ ní ojú ìrán ní òru pé, “Jákọ́bù! Jákọ́bù!”Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
3 Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá níbẹ̀.
4 Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Éjíbítì, èmi yóò sì tún mú ọ pada wá. Ọwọ́ Jósẹ́fù fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.”
5 Nígbà náà ni Jákọ́bù kúrò ní Báá-Ṣébà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mú Jákọ́bù bàbá wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Fáráò fí ránsẹ́ fún ìrìn-àjò rẹ̀:
6 Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun-ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kénánì, Jákọ́bù àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì.
7 Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ obìnrin-gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Éjíbítì.
8 Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (Jákọ́bù àti Ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Éjíbítì:Rúbẹ́nì àkọ́bí Jákọ́bù.