5 ‘Baba mi mú mi búra ó sì wí fún mi pé, “Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú: sin mi sínú ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kénánì.” Nísinsin yìí, jẹ́ kí n lọ kí n sì sìnkú baba mi, lẹ́yìn náà èmi yóò padà wa.’ ”
6 Fáráò wí pé, “Gòkè lọ, kí o sì sin baba rẹ, bí ó tí mú ọ búra.”
7 Báyìí ni Jósẹ́fù gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè Fáráò ni ó sìn ín lọ—àwọn ènìyàn pàtàkì pàtàkì ilé rẹ̀, àti àwọn ènìyàn pàtàkì pàtàkì ilẹ̀ Éjíbítì.
8 Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Jóṣẹ́fù àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Gósénì.
9 Kẹ̀kẹ́ ẹsin àti àwọn ẹlẹ́sin pẹ̀lú gòkè lọ. Àìmọye ènìyàn ni ó lọ.
10 Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà Átadì, ní ẹ̀bá Jọ́dánì, wọn pohùn réré ẹkún; Níbẹ̀ ni Jósẹ́fù sì tún dúró ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ méje.
11 Nígbà tí àwọn ará Kénánì tí ń gbé níbẹ̀ ri i bí wọ́n ti ń sọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Átadì, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Éjíbítì ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Mísíráímù (Ìsọ̀fọ̀ àwọn ará Éjíbítì). Kò sì jìnnà sí Jọ́dánì.