9 Kẹ̀kẹ́ ẹsin àti àwọn ẹlẹ́sin pẹ̀lú gòkè lọ. Àìmọye ènìyàn ni ó lọ.
10 Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà Átadì, ní ẹ̀bá Jọ́dánì, wọn pohùn réré ẹkún; Níbẹ̀ ni Jósẹ́fù sì tún dúró ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ méje.
11 Nígbà tí àwọn ará Kénánì tí ń gbé níbẹ̀ ri i bí wọ́n ti ń sọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Átadì, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Éjíbítì ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Mísíráímù (Ìsọ̀fọ̀ àwọn ará Éjíbítì). Kò sì jìnnà sí Jọ́dánì.
12 Báyìí ni àwọn ọmọ Jákọ́bù ṣe ohun tí baba wọn páṣẹ fún wọn.
13 Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénánì, wọ́n sì sin-ín sínú ihò àpáta tí ó wà ní oko Makipélà, ní tòsí i Mámúrè tí Ábúráhámù rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Éfúrónì ará Hítì, pẹ̀lú ilẹ̀ náà.
14 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú baba rẹ̀ tan, Jóṣẹ́fù padà sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn mìíràn tí ó tẹ̀lé e lọ láti sin baba rẹ̀.
15 Nígbà tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù rí i pé baba wọn kú, wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ bí ó bá ṣe pé Jósẹ́fù sì fi wá sínú ńkọ́, tí ó sì fẹ́ gbẹ̀ṣan gbogbo aburú tí a ti ṣe sí i?”