3 Sì mú méjeméje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á baà lè pa wọ́n mọ́ láàyè ní gbogbo ayé.
4 Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run, kúrò lórí ilẹ̀.”
5 Nóà sì ṣe ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un.
6 Nóà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀.
7 Nóà àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì wọ inú ọkọ láti ṣá àsálà fún ìkún omi.
8 Méjìméjì ni àwọn ẹran tí ó jẹ́ mímọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà,
9 akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Nóà sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà.