6 Nóà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀.
7 Nóà àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì wọ inú ọkọ láti ṣá àsálà fún ìkún omi.
8 Méjìméjì ni àwọn ẹran tí ó jẹ́ mímọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà,
9 akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Nóà sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà.
10 Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé.
11 Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kéjì, tí Nóà pé ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún, ni gbogbo ìṣun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì sí sílẹ̀.
12 Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.