11 Nítorí náà Lọ́tì yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà oòrùn. Òun àti Ábúrámù sì pínyà.
12 Ábúrámù ń gbé ni ilẹ̀ Kénánì, Lọ́tì sì jókòó ní ìlú agbègbè àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Ṣódómù.
13 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ṣódómù jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́sẹ̀ gidigidi ni ìwájú Olúwa.
14 Olúwa sì wí fún Ábúrámù lẹ́yìn ìpínyà òun àti Lọ́tí pé, “Gbé ojú rẹ sókè níṣinṣin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúsù, sí ìlà oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀.
15 Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ní èmi ó fi fún ọ àti irú ọmọ rẹ láéláé.
16 Èmi yóò mú kí irú ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀. Àyàfi bí ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò tó lè ka irú ọmọ rẹ.
17 Dìde, rìn òòró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún.”