6 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun-ìní wọn pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, débi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀.
7 Èdè àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn darandaran Ábúrámù àti ti Lọ́tì. Àwọn ará a Kénánì àti àwọn ará Pérísítì sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà.
8 Ábúrámù sì wí fún Lọ́tì pé, “Mo fẹ́ kí a fòpin sí èdè àìyedè tí ó wà láàrin èmi àti ìwọ àti láàrin àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí ni wá.
9 Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwo lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.”
10 Lọ́tì sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Éjíbítì, ní ọ̀nà Ṣóárì. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Ṣódómù àti Gòmórà run).
11 Nítorí náà Lọ́tì yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà oòrùn. Òun àti Ábúrámù sì pínyà.
12 Ábúrámù ń gbé ni ilẹ̀ Kénánì, Lọ́tì sì jókòó ní ìlú agbègbè àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Ṣódómù.