10 Àfonífojì Ṣídímù sì kún fún kòtò ọ̀dà-ilẹ̀, nígbà tí ọba Ṣódómù àti ọba Gòmórà sì ṣá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà subú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè.
11 Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Ṣódómù àti Gòmórà àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ.
12 Wọ́n sì mú Lọ́tì ọmọ arákùnrin Ábúrámù tí ń gbé ní Ṣódómù àti gbogbo ohun-ìní rẹ̀.
13 Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Ábúrámù, ará Ébérù. Ábúrámù sá ti tẹ̀dó sí igbó igi Óákù tí ó jẹ́ ti Mámúrè ará Ámórì, arákùnrin Ésíkólì àti Ánérì: àwọn ẹni tí ó ń bá Ábúrámù ní àṣepọ̀.
14 Nígbà tí Ábúrámù gbọ́ wí pé, a di Lọ́tì ní ìgbékùn, o kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ́ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó-lé-lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì ènìyàn (318), ó sì lépa wọn títí dé Dánì.
15 Ní ọ̀gànjọ́ òru, Ábúrámù pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Oba, ní àríwá Dámásíkù.
16 Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọ́tì pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tó kù.