3 Lẹ́yín ọdún mẹ́wàá tí Ábúrámù ti ń gbé ni Kénánì ni Ṣáráì mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hágárì, tí í ṣe ará Éjíbítì fún Ábúrámù ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya.
4 Ábúrámù sì bá Ágárì lòpọ̀, ó sì lóyún.Nígbà tí ó sì ti mọ̀ pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sì ní kẹ́gàn ọ̀gá rẹ̀ (Ṣáráì).
5 Nígbà náà ni Ṣáráì wí fún Ábúrámù pé, “Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹmí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀. Kí Olúwa kí ó ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ìwọ.”
6 Ábúrámù dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Ṣáráì fi ìyà jẹ ẹ́, ó sì sá lọ.
7 Ańgẹ́lì Olúwa sì rí Ágáì ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀na tí ó lọ sí Ṣúrì.
8 Ó sì wí pé, “Hágárì, ìránṣẹ́ Ṣáráì, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?”Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sá lọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Ṣáráì ni.”
9 Ańgẹ́lì Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.”