7 Níṣinyìí, dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí pé wòlíì ni, yóò sì gbàdúrà fún ọ, ìwọ yóò sì yè. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá dá a padà, mọ̀ dájú pé ìwọ àti gbogbo ẹni tíí ṣe tìrẹ yóò kú.”
8 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Ábímélékì pe gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà tí ó sì ṣọ gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀ fún wọn, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.
9 Nígbà náà ni Ábímélékì pe Ábúráhámù ó sì wí fún un pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Ẹ̀sẹ̀ wo ni mo sẹ̀ ọ́ tí ìwọ fi mú ìdálẹ́bi ńlá wá sí orí èmi àti ìjọba mi? Kò yẹ kí ìwọ hu irú ìwà yìí sí mi.”
10 Ábímélékì sì bi Ábúráhámù pé, “Kín ló dé tí ìwọ fi ṣe èyí?”
11 Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Mo ṣe èyí nítorí mo rò nínú ara mi pé, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín, ẹ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, pé, ẹ sì le pa mí nítorí aya mi.
12 Yàtọ̀ fún ìyẹn, òtítọ́ ni pé arábìnrin mi ni. Ọmọ baba kan ni wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a kì í ṣe ọmọ ìyá kan. Mo sì fẹ́ ẹ ní aya.
13 Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fi hàn pé ó fẹ́ràn mi: Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, “Arákùnrin rẹ ni mí.” ’ ”