Jẹ́nẹ́sísì 22:3-9 BMY

3 Ábúráhámù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Ísáákì ọmọ rẹ̀, ó sì ṣe igi fún ẹbọ ṣíṣun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún-un.

4 Nígbà tí ó di ọjọ kẹ́ta, Ábúráhámù gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè,

5 Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ọ̀hún-un-nì láti sin Olúwa, a ó sì tún pada wá bá a yín.”

6 Ábúráhámù sì gbé igi ẹbọ ṣíṣun náà ru Ísáákì, òun fúnra rẹ̀ sì mú iná àti ọ̀bẹ. Bí àwọn méjèèjì ti ń lọ,

7 Ísáákì sì sọ fún Ábúráhámù baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.”Ábúráhámù sì da lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.”Ísáákì sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́ àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?”

8 Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ̀-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìn-àjò wọn.

9 Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igiọ lé e lórí, ó sì di Ísáákì ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà.