1 Nígbà náà ni Jákọ́bù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò sẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún-un yín.
2 “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jákọ́bù;Ẹ fetí sí Ísírẹ́lì baba yín.
3 “Rúbẹ́nì, ìwọ ni àkọ́bí mi,agbára mi, ìpìlẹṣẹ̀ ipá mi,títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára.
4 Ẹni ríru bí omi òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́,nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ,lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́(ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lò pọ̀).
5 “Símónì àti Léfì jẹ́ arákùnrin—idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára.
6 Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn,kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn,nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn,wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n.
7 Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ógbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà.Èmi yóò tú wọn ká ní Jákọ́bù,èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Ísírẹ́lì.