Jẹ́nẹ́sísì 14:8-14 BMY

8 Nígbà náà ni ọba Ṣódómù, ọba Gòmórà, ọba Ádímà, ọba Ṣébóímù àti ọba Bélà (èyí ni Ṣóárì), kó àwọn ọmọ ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó-ogun wọn sí àfonífojì Ṣídímù,

9 láti kojú ìjà sí Kedolaómérì ọba Élámù, Tídà ọba Góímù, Ámúráfélì ọba Ṣínárì àti Áríókì ọba Élásà (ọba mẹ́rin kọjú ìjà sí ọba márùn-ún).

10 Àfonífojì Ṣídímù sì kún fún kòtò ọ̀dà-ilẹ̀, nígbà tí ọba Ṣódómù àti ọba Gòmórà sì ṣá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà subú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè.

11 Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Ṣódómù àti Gòmórà àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ.

12 Wọ́n sì mú Lọ́tì ọmọ arákùnrin Ábúrámù tí ń gbé ní Ṣódómù àti gbogbo ohun-ìní rẹ̀.

13 Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Ábúrámù, ará Ébérù. Ábúrámù sá ti tẹ̀dó sí igbó igi Óákù tí ó jẹ́ ti Mámúrè ará Ámórì, arákùnrin Ésíkólì àti Ánérì: àwọn ẹni tí ó ń bá Ábúrámù ní àṣepọ̀.

14 Nígbà tí Ábúrámù gbọ́ wí pé, a di Lọ́tì ní ìgbékùn, o kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ́ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó-lé-lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì ènìyàn (318), ó sì lépa wọn títí dé Dánì.