5 Láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun-ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún-un nítorí Jósẹ́fù. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Pọ́tífà ní, nílé àti lóko.
6 Ó sì fi Jósẹ́fù ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù ṣe àkóṣo ilé e rẹ̀.Josẹ́fù sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀,
7 lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Jósẹ́fù, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lò pọ̀!”
8 Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́.
9 Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?”
10 Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Jósẹ́fù, Jósẹ́fù kọ̀ láti bá a lò pọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà.
11 Ní ọjọ́ kan, Jósẹ́fù lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí.