1 IBUKÚN ni fun ọkunrin na ti kò rìn ni ìmọ awọn enia buburu, ti kò duro li ọ̀na awọn ẹlẹṣẹ, ati ti kò si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgàn.
2 Ṣugbọn didùn-inu rẹ̀ wà li ofin Oluwa; ati ninu ofin rẹ̀ li o nṣe aṣaro li ọsan ati li oru.
3 Yio si dabi igi ti a gbìn si eti ipa odò, ti nso eso rẹ̀ jade li akokò rẹ̀; ewe rẹ̀ kì yio si rẹ̀; ati ohunkohun ti o ṣe ni yio ma ṣe dede.
4 Awọn enia buburu kò ri bẹ̃: ṣugbọn nwọn dabi iyangbo ti afẹfẹ nfẹ lọ.
5 Nitorina awọn enia buburu kì yio dide duro ni idajọ, bẹ̃li awọn ẹlẹṣẹ kì yio le duro li awujọ awọn olododo.
6 Nitori Oluwa mọ̀ ọ̀na awọn olododo: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio ṣegbe.