1 KI Oluwa ki o gbohùn rẹ li ọjọ ipọnju; orukọ Ọlọrun Jakobu ki o dàbobo ọ.
2 Ki o rán iranlọwọ si ọ lati ibi-mimọ́ wá, ki o si tì ọ lẹhin lati Sioni wá.
3 Ki o ranti ẹbọ-ọrẹ rẹ gbogbo, ki o si gbà ẹbọ sisun rẹ.
4 Ki o fi fun ọ gẹgẹ bi ti inu rẹ, ki o si mu gbogbo ìmọ rẹ ṣẹ.
5 Awa o ma kọrin ayọ̀ igbala rẹ, ati li orukọ Ọlọrun wa li awa o fi ọpágun wa de ilẹ; ki Oluwa ki o mu gbogbo ibère rẹ ṣẹ.
6 Nigbayi ni mo to mọ̀ pe Oluwa gbà Ẹni-ororo rẹ̀ là; yio gbọ́ ọ lati ọrun mimọ́ rẹ̀ wá nipa agbara igbala ọwọ ọ̀tun rẹ̀.
7 Awọn ẹlomiran gbẹkẹle kẹkẹ́, awọn ẹlomiran le ẹṣin; ṣugbọn awa o ranti orukọ Oluwa Ọlọrun wa.
8 Nwọn wolẹ, nwọn si ṣubu: ṣugbọn awa dide awa si duro ṣinṣin.
9 Gbani, Oluwa, ki Ọba ki o gbọ nigbati awa ba nkigbe pe e.