O. Daf 132 YCE

Majẹmu Ọlọrun pẹlu Ìdílé Dafidi

1 OLUWA, ranti Dafidi ninu gbogbo ipọnju rẹ̀:

2 Ẹniti o ti bura fun Oluwa, ti o si ṣe ileri ifẹ fun Alagbara Jakobu pe.

3 Nitõtọ, emi kì yio wọ̀ inu agọ ile mi lọ, bẹ̃li emi kì yio gùn ori akete mi;

4 Emi kì yio fi orun fun oju mi, tabi õgbe fun ipenpeju mi,

5 Titi emi o fi ri ibi fun Oluwa, ibujoko fun Alagbara Jakobu.

6 Kiyesi i, awa gburo rẹ̀ ni Efrata: awa ri i ninu oko ẹgàn na.

7 Awa o lọ sinu agọ rẹ̀: awa o ma sìn nibi apoti-itisẹ rẹ̀.

8 Oluwa, dide si ibi isimi rẹ; iwọ, ati apoti agbara rẹ.

9 Ki a fi ododo wọ̀ awọn alufa rẹ: ki awọn enia mimọ rẹ ki o ma hó fun ayọ̀.

10 Nitori ti Dafidi iranṣẹ rẹ, máṣe yi oju ẹni-ororo rẹ pada.

11 Oluwa ti bura nitõtọ fun Dafidi; on kì yio yipada kuro ninu rẹ̀, Ninu iru-ọmọ inu rẹ li emi o gbé kalẹ si ori itẹ́ rẹ.

12 Bi awọn ọmọ rẹ yio ba pa majẹmu mi mọ́ ati ẹri mi ti emi o kọ́ wọn, awọn ọmọ wọn pẹlu yio joko lori itẹ́ rẹ lailai.

13 Nitori ti Oluwa ti yàn Sioni; o ti fẹ ẹ fun ibujoko rẹ̀.

14 Eyi ni ibi isimi mi lailai: nihin li emi o ma gbe; nitori ti mo fẹ ẹ.

15 Emi o bukún onjẹ rẹ̀ pupọ̀-pupọ̀: emi o fi onjẹ tẹ́ awọn talaka rẹ̀ lọrùn.

16 Emi o si fi igbala wọ̀ awọn alufa rẹ̀: awọn enia mimọ́ rẹ̀ yio ma hó fun ayọ̀.

17 Nibẹ li emi o gbe mu iwo Dafidi yọ, emi ti ṣe ilana fitila kan fun ẹni-ororo mi.

18 Awọn ọta rẹ̀ li emi o fi itiju wọ̀: ṣugbọn lara on tikararẹ̀ li ade rẹ̀ yio ma gbilẹ.