1 IWỌ, Oluwa, apata mi li emi o kigbe pè, máṣe dakẹ si mi; bi iwọ ba dakẹ si mi, emi o dabi awọn ti o lọ sinu ihò.
2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi, nigbati mo ba nkigbe pè ọ, nigbati mo ba gbé ọwọ mi soke siha ibi-mimọ́ jùlọ rẹ.
3 Máṣe fà mi lọ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ, ti nsọ̀rọ alafia si aladugbo wọn, ṣugbọn ìwa-ìka mbẹ̀ li ọkàn wọn.
4 Fi fun wọn gẹgẹ bi iṣe wọn, ati gẹgẹ bi ìwa buburu ete wọn, fi fun wọn nipa iṣẹ ọwọ wọn, fi ère wọn fun wọn.
5 Nitori ti nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, tabi iṣẹ ọwọ rẹ̀; on o run wọn, kì yio si gbé wọn ró.
6 Olubukún ni Oluwa, nitoriti o ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi.
7 Oluwa li agbara ati asà mi; on li aiya mi gbẹkẹle, a si nràn mi lọwọ: nitorina inu mi dùn jọjọ: emi o si ma fi orin mi yìn i.
8 Oluwa li agbara wọn, on si li agbara igbala ẹni-ororo rẹ̀.
9 Gbà awọn enia rẹ là, ki o si busi ilẹ-ini rẹ: ma bọ́ wọn pẹlu, ki o si ma gbé wọn leke lailai.