1 ỌLỌRUN, iwọ li Ọlọrun mi; ni kutukutu li emi o ma ṣafẹri rẹ; ongbẹ rẹ ngbẹ ọkàn mi, ẹran-ara mi fà si ọ ni ilẹ gbigbẹ, ati ilẹ ti npongbẹ, nibiti omi kò gbe si.
2 Bayi li emi ti wò ọ ninu ibi-mimọ́, lati ri agbara rẹ ati ogo rẹ.
3 Nitori ti iṣeun-ifẹ rẹ san jù ìye lọ, ète mi yio ma yìn ọ.
4 Bayi li emi o ma fi ibukún fun ọ niwọnbi mo ti wà lãye: emi o ma gbé ọwọ mi soke li orukọ rẹ.
5 Bi ẹnipe ijà ati ọ̀ra bẹ̃ni yio tẹ ọkàn mi lọrun; ẹnu mi yio si ma fi ète ayọ̀ yìn ọ:
6 Nigbati mo ba ranti rẹ lori ẹní mi, ti emi si nṣe aṣaro rẹ ni iṣọ oru.
7 Nitoripe iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi, nitorina li ojiji iyẹ́-apa rẹ li emi o ma yọ̀.
8 Ọkàn mi ntọ̀ ọ lẹhin girigiri: ọwọ ọtún rẹ li o gbé mi ró.
9 Ṣugbọn awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run, nwọn o lọ si iha isalẹ-ilẹ.
10 Nwọn o ti ọwọ idà ṣubu: nwọn o si ṣe ijẹ fun kọ̀lọkọlọ.
11 Ṣugbọn ọba yio ma yọ̀ ninu Ọlọrun; olukuluku ẹniti o nfi i bura ni yio ṣogo: ṣugbọn awọn ti nṣeke li a o pa li ẹnu mọ́.