O. Daf 94 YCE

Ọlọrun Onídàájọ́ Gbogbo Ayé

1 OLUWA, Ọlọrun ẹsan; Ọlọrun ẹsan, fi ara rẹ hàn.

2 Gbé ara rẹ soke, iwọ onidajọ aiye: san ẹsan fun awọn agberaga.

3 Oluwa, yio ti pẹ to ti awọn enia buburu, yio ti pẹ to ti awọn enia buburu yio fi ma leri?

4 Nwọn o ti ma dà ọ̀rọ nù ti nwọn o ma sọ ohun lile pẹ to? ti gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ yio fi ma fi ara wọn leri.

5 Oluwa, nwọn fọ́ awọn enia rẹ tutu, nwọn si nyọ awọn enia-ini rẹ lẹnu.

6 Nwọn pa awọn opó ati alejo, nwọn si pa awọn ọmọ alaini-baba.

7 Sibẹ nwọn wipe, Oluwa kì yio ri i, bẹ̃li Ọlọrun Jakobu kì yio kà a si,

8 Ki oye ki o ye nyin, ẹnyin ope ninu awọn enia: ati ẹnyin aṣiwere, nigbawo li ẹnyin o gbọ́n?

9 Ẹniti o gbin eti, o le ṣe alaigbọ́ bi? ẹniti o da oju, o ha le ṣe alairiran?

10 Ẹniti nnà awọn orilẹ-ède, o ha le ṣe alaiṣe olutọ́? on li ẹniti nkọ́ enia ni ìmọ.

11 Oluwa mọ̀ ìro-inu enia pe: asan ni nwọn.

12 Ibukún ni fun enia na ẹniti iwọ nà, Oluwa, ti iwọ si kọ́ lati inu ofin rẹ wá;

13 Ki iwọ ki o le fun u ni isimi kuro li ọjọ ibi, titi a o fi wà iho silẹ fun enia buburu.

14 Nitoripe Oluwa kì yio ṣa awọn enia rẹ̀ tì, bẹ̃ni kì yio kọ̀ awọn enia-ini rẹ̀ silẹ.

15 Ṣugbọn idajọ yio pada si ododo: gbogbo ọlọkàn diduro ni yio si ma tọ̀ ọ lẹhin.

16 Tani yio dide si awọn oluṣe buburu fun mi? tabi tani yio dide si awọn oniṣẹ ẹ̀ṣe fun mi?

17 Bikoṣe bi Oluwa ti ṣe oluranlọwọ mi; ọkàn mi fẹrẹ joko ni idakẹ.

18 Nigbati mo wipe, Ẹsẹ mi yọ́; Oluwa, ãnu rẹ dì mi mu.

19 Ninu ọ̀pọlọpọ ibinujẹ mi ninu mi, itunu rẹ li o nmu inu mi dùn.

20 Itẹ́ ẹ̀ṣẹ ha le ba ọ kẹgbẹ pọ̀, ti nfi ofin dimọ ìwa-ika?

21 Nwọn kó ara wọn jọ pọ̀ si ọkàn olododo, nwọn si da ẹ̀jẹ alaiṣẹ lẹbi.

22 Ṣugbọn Oluwa li àbo mi; Ọlọrun mi si li apata àbo mi,

23 On o si mu ẹ̀ṣẹ wọn bọ̀ sori ara wọn, yio si ke wọn kuro ninu ìwa-buburu wọn: Oluwa Ọlọrun wa, yio ke wọn kuro.