O. Daf 90 YCE

IWE KẸRIN

Ibi tí Agbára Ẹ̀dá Mọ

Adura Mose, enia Ọlọrun

1 OLUWA, iwọ li o ti nṣe ibujoko wa lati irandiran.

2 Ki a to bí awọn òke nla, ati ki iwọ ki o to dá ilẹ on aiye, ani lati aiye-raiye, iwọ li Ọlọrun.

3 Iwọ sọ enia di ibajẹ; iwọ si wipe, Ẹ pada wá, ẹnyin ọmọ enia.

4 Nitoripe igbati ẹgbẹrun ọdun ba kọja li oju rẹ, bi aná li o ri, ati bi igba iṣọ́ kan li oru.

5 Iwọ kó wọn lọ bi ẹnipe ni ṣiṣan-omi; nwọn dabi orun; ni kutukutu nwọn dabi koriko ti o dagba soke.

6 Ni Kutukutu o li àwọ lara, o si dàgba soke, li asalẹ a ké e lulẹ, o si rọ.

7 Nitori awa di egbé nipa ibinu rẹ, ati nipa ibinu rẹ ara kò rọ̀ wa.

8 Iwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ wa ka iwaju rẹ, ohun ìkọkọ wa mbẹ ninu imọlẹ iwaju rẹ.

9 Nitori ọjọ wa gbogbo nyipo lọ ninu ibinu rẹ: awa nlo ọjọ wa bi alá ti a nrọ́.

10 Adọrin ọdun ni iye ọjọ ọdun wa; bi o si ṣepe nipa ti agbara, bi nwọn ba to ọgọrin ọdun, agbara wọn lãla on ibinujẹ ni; nitori pe a kì o pẹ ke e kuro, awa a si fò lọ.

11 Tali o mọ̀ agbara ibinu rẹ? gẹgẹ bi ẹ̀ru rẹ, bẹ̃ni ibinu rẹ.

12 Bẹ̃ni ki iwọ ki o kọ́ wa lati ma ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọ́n.

13 Pada, Oluwa, yio ti pẹ to? yi ọkàn pada nitori awọn ọmọ-ọdọ rẹ.

14 Fi ãnu rẹ tẹ́ wa li ọrùn ni kutukutu; ki awa ki o le ma yọ̀, ati ki inu wa ki o le ma dùn li ọjọ wa gbogbo.

15 Mu inu wa dùn bi iye ọjọ ti iwọ pọ́n wa loju, ati iye ọdun ti awa ti nri buburu.

16 Jẹ ki iṣẹ rẹ ki o hàn si awọn ọmọ-ọ̀dọ rẹ, ati ogo rẹ si awọn ọmọ wọn.

17 Jẹ ki ẹwà Oluwa Ọlọrun wa ki o wà lara wa: ki iwọ ki o si fi idi iṣẹ ọwọ wa mulẹ lara wa, bẹ̃ni iṣẹ ọwọ wa ni ki iwọ ki o fi idi rẹ̀ mulẹ.