1 EMI o ma fi ibukún fun Oluwa nigbagbogbo: Iyìn rẹ̀ yio ma wà li ẹnu mi titi lai.
2 Ọkàn mi yio ma ṣogo rẹ̀ niti Oluwa: awọn onirẹlẹ yio gbọ́, inu wọn yio si ma dùn.
3 Gbé Oluwa ga pẹlu mi, ki a si jumọ gbé orukọ rẹ̀ leke.
4 Emi ṣe afẹri Oluwa, o si gbohùn mi; o si gbà mi kuro ninu gbogbo ìbẹru mi.
5 Nwọn wò o, imọlẹ si mọ́ wọn: oju kò si tì wọn.
6 Ọkunrin olupọnju yi kigbe pè, Oluwa si gbohùn rẹ̀, o si gbà a ninu gbogbo ipọnju rẹ̀:
7 Angeli Oluwa yi awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ ká, o si gbà wọn.
8 Tọ́ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni Oluwa: alabukún fun li ọkunrin na ti o gbẹkẹle e.
9 Ẹ bẹ̀ru Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: nitoriti kò si aini fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀,
10 Awọn ọmọ kiniun a ma ṣe alaini, ebi a si ma pa wọn: ṣugbọn awọn ti nwá Oluwa, kì yio ṣe alaini ohun ti o dara.
11 Wá, ẹnyin ọmọ, fi eti si mi: emi o kọ́ nyin li ẹ̀ru Oluwa.
12 Ọkunrin wo li o nfẹ ìye, ti o si nfẹ ọjọ pipọ, ki o le ma ri rere?
13 Pa ahọn rẹ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ kuro li ẹ̀tan sisọ.
14 Lọ kuro ninu ibi, ki o si ma ṣe rere; ma wá alafia, ki o si lepa rẹ̀.
15 Oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, eti rẹ̀ si ṣi si igbe wọn.
16 Oju Oluwa kan si awọn ti nṣe buburu, lati ke iranti wọn kuro lori ilẹ.
17 Awọn olododo nke, Oluwa si gbọ́, o si yọ wọn jade ninu iṣẹ́ wọn gbogbo.
18 Oluwa mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là.
19 Ọ̀pọlọpọ ni ipọnju olododo; ṣugbọn Oluwa gbà a ninu wọn gbogbo.
20 O pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́; kò si ọkan ti o ṣẹ́ ninu wọn.
21 Ibi ni yio pa enia buburu; ati awọn ti o korira olododo yio jẹbi.
22 Oluwa rà ọkàn awọn iranṣẹ rẹ̀; ọkan ninu awọn ti o gbẹkẹle e kì yio jẹbi.