1 ỌLỌRUN, ṣãnu fun mi: nitoriti enia nfẹ gbe mi mì; o mba mi jà lojojumọ, o nni mi lara.
2 Awọn ọta mi nfẹ igbe mi mì lojojumọ: nitori awọn ti nfi igberaga ba mi ja pọ̀.
3 Nigbati ẹ̀ru ba mbà mi, emi o gbẹkẹle ọ.
4 Nipa Ọlọrun li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀, Ọlọrun li emi o gbẹkẹ mi le, emi kì yio bèru: kili ẹran-ara le ṣe si mi.
5 Lojojumọ ni nwọn nlọ́ ọ̀rọ mi: ibi ni gbogbo ìro inu wọn si mi:
6 Nwọn kó ara wọn jọ, nwọn ba, nwọn kiyesi ìrin mi, nwọn ti nṣọ̀na ọkàn mi.
7 Nwọn ha le ti ipa aiṣedede là? ni ibinu, bi awọn enia na lulẹ̀, Ọlọrun.
8 Iwọ nka ìrìnkiri mi: fi omije mi sinu igo rẹ: nwọn ko ha si ninu iwe rẹ bi?
9 Li ọjọ ti mo ba kigbe, nigbana li awọn ọta mi yio pẹhinda: eyi li emi mọ̀: nitoripe Ọlọrun wà fun mi.
10 Nipa Ọlọrun li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀: nipa Oluwa li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀.
11 Ọlọrun li emi gbẹkẹ mi le, emi kì yio bẹ̀ru kili enia le ṣe si mi.
12 Ẹjẹ́ rẹ mbẹ lara mi, Ọlọrun: emi o fi iyìn fun ọ.
13 Nitoripe iwọ li o ti gbà ọkàn mi lọwọ ikú: iwọ ki yio ha gbà ẹsẹ mi lọwọ iṣubu? ki emi ki o le ma rìn niwaju Ọlọrun ni imọlẹ awọn alãye?