O. Daf 147 YCE

Ọlọrun Alágbára

1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa: nitori ohun rere ni lati ma kọ orin iyìn si Ọlọrun wa: nitori ti o dùn, iyìn si yẹ.

2 Oluwa li o kọ́ Jerusalemu: on li o kó awọn ifọnkalẹ Israeli jọ.

3 O mu awọn onirora aiya lara da: o di ọgbẹ wọn:

4 O ka iye awọn ìrawọ; o si sọ gbogbo wọn li orukọ.

5 Oluwa wa tobi, ati alagbara nla: oye rẹ̀ kò li opin.

6 Oluwa gbé awọn onirẹlẹ soke: o rẹ̀ awọn enia buburu si ilẹyilẹ.

7 Ẹ fi ọpẹ kọrin si Oluwa; kọrin iyìn si Ọlọrun wa lara duru:

8 Ẹniti o fi awọsanma bò oju ọrun, ẹniti o pèse òjo fun ilẹ, ti o mu koriko dàgba lori awọn òke nla.

9 O fi onjẹ ẹranko fun u ati fun ọmọ iwò ti ndún.

10 Kò ṣe inudidùn si agbara ẹṣin: kò ṣe inudidùn si ẹsẹ ọkunrin.

11 Oluwa nṣe inudidùn si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, si awọn ti nṣe ireti ãnu rẹ̀.

12 Yìn Oluwa, iwọ Jerusalemu; yìn Ọlọrun rẹ, iwọ Sioni.

13 Nitori ti o ti mu ọpá-idabu ẹnu-bode rẹ le; o ti busi i fun awọn ọmọ rẹ ninu rẹ.

14 O fi alafia ṣe àgbegbe rẹ, o si fi alikama didara-jù kún ọ.

15 O rán aṣẹ rẹ̀ jade wá si aiye; ọ̀rọ rẹ̀ sure tete.

16 O fi òjo-didì funni bi irun-agutan, o si fún ìri-didì ká bi ẽrú.

17 O dà omi didì rẹ̀ bi òkele; tali o le duro niwaju otutu rẹ̀.

18 O rán ọ̀rọ rẹ̀ jade, o si mu wọn yọ́; o mu afẹfẹ rẹ̀ fẹ, omi si nṣàn.

19 O fi ọ̀rọ rẹ̀ hàn fun Jakobu, aṣẹ rẹ̀ ati idajọ rẹ̀ fun Israeli.

20 Kò ba orilẹ-ède kan ṣe bẹ̃ ri; bi o si ṣe ti idajọ rẹ̀ ni, nwọn kò mọ̀ wọn. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.