O. Daf 66 YCE

Orin Ìyìn ati Ọpẹ́

1 Ẹ hó iho ayọ̀ si Ọlọrun, ẹnyin ilẹ gbogbo:

2 Ẹ kọrin ọlá orukọ rẹ̀: ẹ mu iyìn rẹ̀ li ogo.

3 Ẹ wi fun Ọlọrun pe, Iwọ ti li ẹ̀ru to ninu iṣẹ rẹ! nipa ọ̀pọ agbara rẹ li awọn ọta rẹ yio fi ori wọn balẹ fun ọ.

4 Gbogbo aiye ni yio ma sìn ọ, nwọn o si ma kọrin si ọ; nwọn o ma kọrin si orukọ rẹ.

5 Ẹ wá wò iṣẹ Ọlọrun, o li ẹ̀ru ni iṣe rẹ̀ si awọn ọmọ enia.

6 O sọ okun di ilẹ gbigbẹ: nwọn fi ẹsẹ là odò já: nibẹ li awa gbe yọ̀ ninu rẹ̀.

7 O jọba nipa agbara rẹ̀ lailai; oju rẹ̀ nwò awọn orilẹ-ède: ki awọn ọlọtẹ ki o máṣe gbé ara wọn ga.

8 Ẹ fi ibukún fun Ọlọrun wa, ẹnyin enia, ki ẹ si mu ni gbọ́ ohùn iyìn rẹ̀.

9 Ẹniti o mu ẹmi wa wà lãye, ti kò si jẹ ki ẹsẹ wa ki o yẹ̀.

10 Ọlọrun, nitori ti iwọ ti ridi wa: iwọ ti dan wa wò, bi ã ti idan fadaka wò.

11 Iwọ mu wa wọ̀ inu àwọn; iwọ fi ipọnju le wa li ẹgbẹ.

12 Iwọ mu awọn enia gùn wa li ori: awa nwọ inu iná ati omi lọ, ṣugbọn iwọ mu wa jade wá si ibi irọra.

13 Emi o lọ sinu ile rẹ ti emi ti ẹbọ sisun: emi o san ẹjẹ́ mi fun ọ,

14 Ti ète mi ti jẹ́, ti ẹnu si ti sọ, nigbati mo wà ninu ipọnju.

15 Emi o ru ẹbọ sisun ọlọra si ọ, pẹlu õrùn ọrá àgbo; emi o rubọ akọ-malu pẹlu ewurẹ.

16 Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, emi o sọ ohun ti o ṣe fun ọkàn mi.

17 Emi fi ẹnu mi kigbe pè e, emi o si fi àhọn mi buyin fun u.

18 Bi emi ba gbà ẹ̀ṣẹ li aiya mi, Oluwa kì yio gbohùn mi:

19 Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun ti gbohùn mi: o si ti fi eti si ohùn adura mi.

20 Olubukún li Ọlọrun, ti kò yi adura mi pada kuro, tabi ãnu rẹ̀ kuro lọdọ mi.