O. Daf 17 YCE

Adura fún Ìdáláre

1 GBỌ́ otiọ́, Oluwa, fiyesi igbe mi, fi eti si adura mi, ti kò ti ète ẹ̀tan jade.

2 Jẹ ki idajọ mi ki o ma ti iwaju rẹ jade wá: jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ohun ti o ṣe dẽde.

3 Iwọ ti dan aiya mi wò; iwọ ti bẹ̀ ẹ wò li oru; iwọ ti wadi mi, iwọ kò ri nkan; emi ti pinnu rẹ̀ pe, ẹnu mi kì yio ṣẹ̀.

4 Niti iṣẹ enia, nipa ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ emi ti pa ara mi mọ́ kuro ni ipa alaparun.

5 Fi ìrin mi le ilẹ ni ipa rẹ, ki atẹlẹ ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀.

6 Emi ti nkepè ọ, nitori pe iwọ o gbohùn mi, Ọlọrun: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbọ́ ọ̀rọ mi:

7 Fi iṣeun ifẹ iyanu rẹ hàn, iwọ ti o fi ọwọ ọtún rẹ gbà awọn ti o gbẹkẹle ọ là, lọwọ awọn ti o dide si wọn.

8 Pa mi mọ́ bi ọmọ-oju, pa mi mọ́ labẹ ojiji iyẹ-apá rẹ,

9 Lọwọ awọn enia buburu ti nfõró mi, lọwọ awọn ọta-iyọta mi, ti o yi mi kakiri.

10 Nwọn fi ọ̀ra sé aiya wọn, ẹnu wọn ni nwọn fi nsọ̀rọ igberaga.

11 Nwọn ti yi wa ká nisisiyi ninu ìrin wa; nwọn ti gbé oju wọn le ati wọ́ wa silẹ:

12 Bi kiniun ti nṣe iwọra si ohun ọdẹ rẹ̀, ati bi ọmọ kiniun ti o mba ni ibi ìkọkọ.

13 Dide, Oluwa, ṣaju rẹ̀, rẹ̀ ẹ silẹ: gbà ọkàn mi lọwọ awọn enia buburu, ti iṣe idà rẹ:

14 Lọwọ awọn enia nipa ọwọ rẹ, Oluwa, lọwọ awọn enia aiye, ti nwọn ni ipin wọn li aiye yi, ati ikùn ẹniti iwọ fi ohun iṣura rẹ ìkọkọ kún: awọn ọmọ wọn pọ̀n nwọn a si fi iyokù ini wọn silẹ fun awọn ọmọ-ọwọ́ wọn.

15 Bi o ṣe ti emi ni emi o ma wò oju rẹ li ododo: àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba jí.