O. Daf 55 YCE

Adura Ẹni tí Ọ̀rẹ́ Dà

1 FETI si adura mi, Ọlọrun; má si ṣe fi ara rẹ pamọ kuro ninu ẹ̀bẹ mi.

2 Fiye si mi, ki o si da mi lohùn: ara mi kò lelẹ ninu aroye mi, emi si npariwo;

3 Nitori ohùn ọta nì, nitori inilara enia buburu: nitoriti nwọn mu ibi ba mi, ati ni ibinu, nwọn dẹkun fun mi.

4 Aiya dùn mi gidigidi ninu mi: ipaiya ikú si ṣubu lù mi.

5 Ibẹ̀ru ati ìwárìrì wá si ara mi, ati ibẹ̀ru ikú bò mi mọlẹ.

6 Emi si wipe, A! iba ṣe pe emi ni iyẹ-apa bi àdaba! emi iba fò lọ, emi a si simi.

7 Kiyesi i, emi iba rìn lọ si ọ̀na jijin rére, emi a si ma gbe li aginju.

8 Emi iba yara sa asala mi kuro ninu ẹfufu lile ati iji na.

9 Oluwa, ṣe iparun, ki o si yà wọn li ahọn: nitori ti mo ri ìwa agbara ati ijà ni ilu na.

10 Ọsan ati oru ni nwọn fi nrìn odi rẹ̀ kiri: ìwa-ika pẹlu ati ikãnu mbẹ li arin rẹ̀.

11 Ìwa buburu mbẹ li arin rẹ̀: ẹ̀tan ati eke kò kuro ni igboro rẹ̀.

12 Nitoriti kì iṣe ọta li o gàn mi: njẹ emi iba pa a mọra: bẹ̃ni kì iṣe ẹniti o korira mi li o gbé ara rẹ̀ ga si mi; njẹ emi iba fi ara mi pamọ́ kuro lọdọ rẹ̀:

13 Ṣugbọn iwọ ni, ọkunrin ọ̀gba mi, amọ̀na mi, ati ojulumọ mi.

14 Awa jumọ gbimọ didùn, awa si kẹgbẹ rìn wọ̀ ile Ọlọrun lọ.

15 Ki ikú ki o dì wọn mu, ki nwọn ki o si lọ lãye si isa-okú: nitori ti ìwa buburu mbẹ ni ibujoko wọn, ati ninu wọn.

16 Bi o ṣe ti emi ni, emi o kepè Ọlọrun; Oluwa yio si gbà mi.

17 Li alẹ, li owurọ, ati li ọsan, li emi o ma gbadura, ti emi o si ma kigbe kikan: on o si gbohùn mi.

18 O ti gbà ọkàn mi silẹ li alafia lọwọ ogun ti o ti dó tì mi: nitoripe pẹlu ọ̀pọlọpọ enia ni nwọn dide si mi.

19 Ọlọrun yio gbọ́, yio si pọ́n wọn loju, ani ẹniti o ti joko lati igbani. Nitoriti nwọn kò ni ayipada, nwọn kò si bẹ̀ru Ọlọrun.

20 O ti nà ọwọ rẹ̀ si iru awọn ti o wà li alafia pẹlu rẹ̀: o ti dà majẹmu rẹ̀.

21 Ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ kunna jù ori-amọ lọ, ṣugbọn ogun jija li o wà li aiya rẹ̀: ọ̀rọ rẹ̀ kunna jù ororo lọ, ṣugbọn idà fifayọ ni nwọn.

22 Kó ẹrù rẹ lọ si ara Oluwa, on ni yio si mu ọ duro: on kì yio jẹ ki ẹsẹ olododo ki o yẹ̀ lai.

23 Ṣugbọn iwọ, Ọlọrun, ni yio mu wọn sọkalẹ lọ si iho iparun: awọn enia ẹ̀jẹ ati enia ẹ̀tan kì yio pe àbọ ọjọ wọn; ṣugbọn emi o gbẹkẹle ọ.