O. Daf 119 YCE

Òfin OLUWA

1 IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa.

2 Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo.

3 Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀.

4 Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi.

5 Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́!

6 Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo.

7 Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ.

8 Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata.

Pípa Òfin OLUWA mọ́

9 Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

10 Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ.

11 Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ.

12 Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ.

13 Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ.

14 Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀.

15 Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ.

16 Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ.

Ayọ̀ ninu Òfin OLUWA

17 Fi ọ̀pọlọpọ ba iranṣẹ rẹ ṣe, ki emi ki o le wà lãye, ki emi ki o le ma pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

18 Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ.

19 Alejo li emi li aiye: máṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fun mi.

20 Aiya mi bù nitori ifojusọna si idajọ rẹ nigbagbogbo.

21 Iwọ ti ba awọn agberaga wi, ti a ti fi gégun, ti o ti ṣina kuro nipa aṣẹ rẹ.

22 Mu ẹ̀gan ati àbuku kuro lara mi; nitoriti emi ti pa ẹri rẹ mọ́.

23 Awọn ọmọ-alade joko pẹlu, nwọn nsọ̀rọ mi: ṣugbọn iranṣẹ rẹ nṣe àṣaro ninu ilana rẹ:

24 Ẹri rẹ pẹlu ni didùn-inu mi ati ìgbimọ mi.

Ìpinnu láti Pa Òfin OLUWA mọ́

25 Ọkàn mi lẹ̀ mọ́ erupẹ: iwọ sọ mi di ãye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

26 Emi ti rohin ọ̀na mi, iwọ si gbohùn mi: mã kọ́ mi ni ilana rẹ.

27 Mu oye ọ̀na ẹkọ́ rẹ ye mi: bẹ̃li emi o ma ṣe aṣaro iṣẹ iyanu rẹ.

28 Ọkàn mi nrọ fun ãrẹ̀: iwọ mu mi lara le gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

29 Mu ọ̀na eke kuro lọdọ mi: ki o si fi ore-ọfẹ fi ofin rẹ fun mi.

30 Emi ti yàn ọ̀na otitọ: idajọ rẹ ni mo fi lelẹ niwaju mi.

31 Emi ti faramọ ẹri rẹ: Oluwa, máṣe dojutì mi.

32 Emi o ma sare li ọ̀na aṣẹ rẹ, nitori iwọ bùn aiya mi laye.

Adura fún Òye

33 Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o si ma pa a mọ́ de opin.

34 Fun mi li oye, emi o si pa ofin rẹ mọ́; nitõtọ, emi o ma kiyesi i tinutinu mi gbogbo.

35 Mu mi rìn ni ipa aṣẹ rẹ; nitori ninu rẹ̀ ni didùn inu mi.

36 Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro.

37 Yi oju mi pada kuro lati ma wò ohun asan; mu mi yè li ọna rẹ.

38 Fi ọ̀rọ rẹ mulẹ si iranṣẹ rẹ, ti iṣe ti ìbẹru rẹ̀.

39 Yi ẹ̀gan mi pada ti mo bẹ̀ru: nitori ti idajọ rẹ dara.

40 Kiyesi i, ọkàn mi ti fà si ẹkọ́ rẹ: sọ mi di ãye ninu ododo rẹ.

Gbígbẹ́kẹ̀lé ninu Òfin OLUWA

41 Jẹ ki ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá pẹlu, Oluwa, ani igbala rẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

42 Bẹ̃li emi o ni ọ̀rọ ti emi o fi da ẹni ti ngàn mi lohùn; nitori mo gbẹkẹle ọ̀rọ rẹ.

43 Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ.

44 Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai.

45 Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ.

46 Emi o si ma sọ̀rọ ẹri rẹ niwaju awọn ọba, emi kì yio si tiju.

47 Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ.

48 Ọwọ mi pẹlu li emi o gbe soke si aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ; emi o si ma ṣe Ìṣàrò-ìlànà rẹ.

Igbẹkẹ le ninu Òfin OLUWA

49 Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti.

50 Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye.

51 Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ.

52 Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu.

53 Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ.

54 Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi.

55 Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́.

56 Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́.

Ìfọkànsí Òfin OLUWA

57 Oluwa, iwọ ni ipin mi: emi ti wipe, emi o pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

58 Emi ti mbẹ̀bẹ oju-rere rẹ tinutinu mi gbogbo: ṣãnu fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

59 Emi rò ọ̀na mi, mo si yi ẹsẹ mi pada si ẹri rẹ.

60 Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́.

61 Okùn awọn enia buburu ti yi mi ka: ṣugbọn emi kò gbagbe ofin rẹ.

62 Lãrin ọganjọ emi o dide lati dupẹ fun ọ nitori ododo idajọ rẹ.

63 Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹ̀ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ́ rẹ mọ́.

64 Oluwa, aiye kún fun ãnu rẹ: kọ́ mi ni ilana rẹ.

Iyebíye ni Òfin OLUWA

65 Iwọ ti nṣe rere fun iranṣẹ rẹ Oluwa, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

66 Kọ́ mi ni ìwa ati ìmọ̀ rere; nitori ti mo gbà aṣẹ rẹ gbọ́.

67 Ki a to pọ́n mi loju emi ti ṣina: ṣugbọn nisisiyi emi ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

68 Iwọ ṣeun iwọ si nṣe rere; kọ́ mi ni ilana rẹ.

69 Awọn agberaga ti hùmọ eke si mi: ṣugbọn emi o pa ẹkọ́ rẹ mọ́ tinutinu mi gbogbo.

70 Aiya wọn sebọ bi ọrá; ṣugbọn emi o ṣe inu-didùn ninu ofin rẹ.

71 O dara fun mi ti a pọ́n mi loju; ki emi ki o le kọ́ ilana rẹ.

72 Ofin ẹnu rẹ dara fun mi jù ẹgbẹgbẹrun wura ati fadaka lọ.

Òdodo ni Òfin OLUWA

73 Ọwọ rẹ li o ti da mi, ti o si ṣe àworan mi: fun mi li oye, ki emi ki o le kọ́ aṣẹ rẹ.

74 Inu awọn ti o bẹ̀ru rẹ yio dùn, nigbati nwọn ba ri mi; nitori ti mo ti reti li ọ̀rọ rẹ.

75 Oluwa, emi mọ̀ pe, ododo ni idajọ rẹ, ati pe li otitọ ni iwọ pọ́n mi loju.

76 Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iṣeun-ãnu rẹ ki o mã ṣe itunu mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ si iranṣẹ rẹ.

77 Jẹ ki irọnu ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá, ki emi ki o le yè: nitori ofin rẹ ni didùn-inu mi.

78 Jẹ ki oju ki o tì agberaga; nitori ti nwọn ṣe arekereke si mi li ainidi: ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ.

79 Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru rẹ ki o yipada si mi, ati awọn ti o ti mọ̀ ẹri rẹ.

80 Jẹ ki aiya mi ki o pé ni ilana rẹ; ki oju ki o máṣe tì mi.

Adura Ìdáǹdè

81 Ọkàn mi ndaku fun igbala rẹ; ṣugbọn emi ni ireti li ọ̀rọ rẹ.

82 Oju mi ṣofo nitori ọ̀rọ rẹ, wipe, Nigbawo ni iwọ o tù mi ninu?

83 Nitori ti emi dabi igo-awọ loju ẽfin; ṣugbọn emi kò gbagbe ilana rẹ.

84 Ijọ melo li ọjọ iranṣẹ rẹ? nigbawo ni iwọ o ṣe idajọ lara awọn ti nṣe inunibini si mi?

85 Awọn agberaga ti wà ìho silẹ dè mi, ti kì iṣe gẹgẹ bi ofin rẹ.

86 Otitọ li aṣẹ rẹ gbogbo: nwọn fi arekereke ṣe inunibini si mi: iwọ ràn mi lọwọ.

87 Nwọn fẹrẹ run mi li ori ilẹ; ṣugbọn emi kò kọ ẹkọ́ rẹ silẹ.

88 Sọ mi di ãye gẹgẹ bi iṣeun-ãnu rẹ; bẹ̃li emi o pa ẹri ẹnu rẹ mọ́.

Igbagbọ ninu Òfin OLUWA

89 Oluwa, lai, ọ̀rọ rẹ kalẹ li ọrun.

90 Lati iran-diran li otitọ rẹ; iwọ ti fi idi aiye mulẹ, o si duro.

91 Nwọn duro di oni nipa idajọ rẹ: nitori pe iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn.

92 Bikoṣepe bi ofin rẹ ti ṣe inu-didùn mi, emi iba ti ṣegbe ninu ipọnju mi.

93 Lai emi kì yio gbagbe ẹkọ́ rẹ; nitori pe awọn ni iwọ fi sọ mi di ãye.

94 Tirẹ li emi, gbà mi; nitori ti emi wá ẹkọ́ rẹ.

95 Awọn enia buburu ti duro dè mi lati pa mi run: ṣugbọn emi o kiyesi ẹri rẹ.

96 Emi ti ri opin ohun pipé gbogbo: ṣugbọn aṣẹ rẹ gbõro gidigidi.

Ìfẹ́ sí Òfin OLUWA

97 Emi ti fẹ ofin rẹ to! iṣaro mi ni li ọjọ gbogbo.

98 Nipa aṣẹ rẹ iwọ mu mi gbọ́n jù awọn ọta mi lọ: nitori ti o wà pẹlu mi lailai.

99 Emi ni iyè ninu jù gbogbo awọn olukọ mi lọ, nitoripe ẹri rẹ ni iṣaro mi.

100 Oye ye mi jù awọn àgba lọ, nitori ti mo pa ẹkọ́ rẹ mọ́.

101 Mo ti fà ẹsẹ mi sẹhin kuro nipa ọ̀na ibi gbogbo, ki emi ki o le pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

102 Emi kò yà kuro ni idajọ rẹ: nitoripe iwọ li o kọ́ mi.

103 Ọ̀rọ rẹ ti dùn mọ́ mi li ẹnu to! jù oyin lọ li ẹnu mi!

104 Nipa ẹkọ́ rẹ emi ni iyè ninu: nitorina mo korira ọ̀na eke gbogbo.

Ìmọ́lẹ̀ láti Inú Òfin OLUWA

105 Ọ̀rọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ̀ mi, ati imọlẹ si ipa ọ̀na mi.

106 Emi ti bura, emi o si mu u ṣẹ, pe, emi o pa idajọ ododo rẹ mọ́.

107 A pọ́n mi loju gidigidi: Oluwa sọ mi di ãye, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

108 Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, gbà ọrẹ atinuwa ẹnu mi, ki o si kọ́ mi ni idajọ rẹ.

109 Ọkàn mi wà li ọwọ mi nigbagbogbo: emi kò si gbagbe ofin rẹ.

110 Awọn enia buburu ti dẹkun silẹ fun mi: ṣugbọn emi kò ṣina kuro nipa ẹkọ́ rẹ.

111 Ẹri rẹ ni ogún mi lailai: nitori awọn li ayọ̀ inu mi.

112 Emi ti fà aiya mi si ati pa ilana rẹ mọ́ nigbagbogbo, ani de opin.

Ààbò ninu Òfin OLUWA

113 Emi korira oniye meji: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ.

114 Iwọ ni ibi ipamọ́ mi ati asà mi: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ.

115 Kuro lọdọ mi, ẹnyin oluṣe-buburu: emi o si pa ofin Ọlọrun mi mọ́.

116 Gbé mi soke gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, ki emi ki o le yè: ki o má si jẹ ki oju ireti mi ki o tì mi.

117 Gbé mi soke, emi o si wà li ailewu: emi o si juba ìlana rẹ nigbagbogbo.

118 Iwọ ti tẹ̀ gbogbo awọn ti o ṣina kuro ninu ilana rẹ mọlẹ: nitori pe ẹ̀tan ni ironu wọn.

119 Iwọ ṣá gbogbo awọn enia buburu aiye tì bi ìdarọ́: nitorina emi fẹ ẹri rẹ.

120 Ara mi warìri nitori ìbẹru rẹ; emi si bẹ̀ru idajọ rẹ.

Pípa Òfin OLUWA mọ́

121 Emi ti ṣe idajọ ati ododo: iwọ kì yio jọwọ mi lọwọ fun awọn aninilara mi.

122 Ṣe onigbọwọ fun iranṣẹ rẹ fun rere: máṣe jẹ ki awọn agberaga ki o ni mi lara.

123 Oju kún mi nitori igbala rẹ, ati nitori ọ̀rọ ododo rẹ.

124 Ṣe si iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi ãnu rẹ, ki o si kọ́ mi ni ilana rẹ.

125 Iranṣẹ rẹ li emi: fun mi li oye, emi o si mọ̀ ẹri rẹ.

126 Oluwa, o to akokò fun ọ lati ṣiṣẹ: nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo.

127 Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ.

128 Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke.

Ìfẹ́ láti Pa Òfin OLUWA Mọ́

129 Iyanu li ẹri rẹ: nitorina li ọkàn mi ṣe pa wọn mọ́.

130 Ifihan ọ̀rọ rẹ funni ni imọlẹ; o si fi oye fun awọn òpe.

131 Emi yà ẹnu mi, emi mí hẹlẹ: nitori ti ọkàn mi fà si aṣẹ rẹ.

132 Iwọ bojuwò mi; ki o si ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣe rẹ si awọn ti o fẹ orukọ rẹ.

133 Fi iṣisẹ mi mulẹ ninu ọ̀rọ rẹ: ki o má si jẹ ki ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ki o jọba lori mi.

134 Gbà mi lọwọ inilara enia; bẹ̃li emi o si ma pa ẹkọ́ rẹ mọ́.

135 Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara; ki o si kọ mi ni ilana rẹ.

136 Odò omi ṣàn silẹ li oju mi nitori nwọn kò pa ofin rẹ mọ́.

Òtítọ́ ni Òfin OLUWA

137 Olododo ni iwọ, Oluwa, ati diduro-ṣinṣin ni idajọ rẹ.

138 Iwọ paṣẹ ẹri rẹ li ododo ati otitọ gidigidi.

139 Itara mi ti pa mi run nitori ti awọn ọta mi ti gbagbe ọ̀rọ rẹ.

140 Funfun gbò li ọ̀rọ rẹ: nitorina ni iranṣẹ rẹ ṣe fẹ ẹ.

141 Emi kere ati ẹni ẹ̀gan ni: ṣugbọn emi kò gbagbe ẹkọ́ rẹ.

142 Ododo rẹ ododo lailai ni, otitọ si li ofin rẹ.

143 Iyọnu ati àrokan dì mi mu: ṣugbọn aṣẹ rẹ ni inu-didùn mi.

144 Ododo ẹri rẹ aiye-raiye ni: fun mi li oye, emi o si yè.

Adura Ìdáǹdè

145 Tinu-tinu mi gbogbo ni mo fi kigbe; Oluwa, da mi lohùn; emi o pa ilana rẹ mọ́.

146 Emi kigbe si ọ; gbà mi là, emi o si ma pa ẹri rẹ mọ́.

147 Emi ṣaju kutukutu owurọ, emi ke: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ.

148 Oju mi ṣaju iṣọ-oru, ki emi ki o le ma ṣe iṣaro ninu ọ̀rọ rẹ.

149 Gbohùn mi gẹgẹ bi ãnu rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ.

150 Awọn ti nlepa ìwa-ika sunmọ itosi: nwọn jina si ofin rẹ.

151 Oluwa, iwọ wà ni itosi: otitọ si ni gbogbo aṣẹ rẹ.

152 Lati inu ẹri rẹ, emi ti mọ̀ nigba atijọ pe, iwọ ti fi idi wọn mulẹ lailai.

Ẹ̀bẹ̀ fún Ìrànlọ́wọ́

153 Wò ipọnju mi, ki o si gbà mi: nitori ti emi kò gbagbe ofin rẹ.

154 Gbà ẹjọ mi rò, ki o rà mi pada: sọ mi di ãye nipa ọ̀rọ rẹ.

155 Igbala jina si awọn enia buburu: nitori ti nwọn kò wá ilana rẹ.

156 Ọ̀pọ ni irọnu ãnu rẹ, Oluwa: sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ.

157 Ọ̀pọ li awọn oninunibini mi ati awọn ọta mi; ṣugbọn emi kò fà sẹhin kuro ninu ẹri rẹ.

158 Emi wò awọn ẹlẹtan, inu mi si bajẹ; nitori ti nwọn kò pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

159 Wò bi emi ti fẹ ẹkọ́ rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi ãnu rẹ.

160 Otitọ ni ipilẹṣẹ ọ̀rọ rẹ; ati olukulùku idajọ ododo rẹ duro lailai.

Fífi Ara Ẹni fún Òfin OLUWA

161 Awọn ọmọ-alade ṣe inunibini si mi li ainidi: ṣugbọn ọkàn mi warìri nitori ọ̀rọ rẹ.

162 Emi yọ̀ si ọ̀rọ rẹ, bi ẹniti o ri ikogun pupọ.

163 Emi korira, mo si ṣe họ̃ si eke ṣiṣe: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ.

164 Nigba meje li õjọ li emi nyìn ọ nitori ododo idajọ rẹ.

165 Alafia pupọ̀ li awọn ti o fẹ ofin rẹ ni: kò si si ohun ikọsẹ fun wọn.

166 Oluwa, emi ti nreti igbala rẹ, emi si ṣe aṣẹ rẹ.

167 Ọkàn mi ti pa ẹri rẹ mọ́; emi si fẹ wọn gidigidi.

168 Emi ti npa ẹkọ́ ati ẹri rẹ mọ́; nitori ti gbogbo ọ̀na mi mbẹ niwaju rẹ.

Adura Ìrànlọ́wọ́

169 Oluwa, jẹ ki ẹkún mi ki o sunmọ iwaju rẹ: fun mi li oye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

170 Jẹ ki ẹ̀bẹ mi ki o wá siwaju rẹ: gbà mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

171 Ete mi yio sọ iyìn jade, nigbati iwọ ba ti kọ́ mi ni ilana rẹ.

172 Ahọn mi yio sọ niti ọ̀rọ rẹ: nitori pe ododo ni gbogbo aṣẹ rẹ.

173 Jẹ ki ọwọ rẹ ki o ràn mi lọwọ; nitori ti mo ti yàn ẹkọ rẹ.

174 Oluwa, ọkàn mi ti fà si igbala rẹ; ofin rẹ si ni didùn-inu mi.

175 Jẹ ki ọkàn mi ki o wà lãye, yio si ma yìn ọ; si jẹ ki idajọ rẹ ki o ma ràn mi lọwọ.

176 Emi ti ṣina kiri bi agutan ti o nù; wá iranṣẹ rẹ nitori ti emi kò gbagbe aṣẹ rẹ.