O. Daf 105 YCE

Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa? ẹ pè orukọ rẹ̀: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia.

2 Ẹ kọrin si i, ẹ kọ orin mimọ́ si i: ẹ ma sọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ̀ gbogbo.

3 Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki aiya awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀.

4 Ẹ ma wá Oluwa ati ipá rẹ̀: ẹ ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo.

5 Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe; iṣẹ àmi rẹ̀ ati idajọ ẹnu rẹ̀;

6 Ẹnyin iru-ọmọ Abrahamu iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu, ayanfẹ rẹ̀.

7 Oluwa, on li Ọlọrun wa: idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye.

8 O ti ranti majẹmu rẹ̀ lailai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran.

9 Majẹmu ti o ba Abrahamu dá, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki;

10 O si gbé eyi na kalẹ li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye.

11 Pe, iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin.

12 Nigbati o ṣe pe kiun ni nwọn wà ni iye; nitõtọ, diẹ kiun, nwọn si ṣe alejo ninu rẹ̀.

13 Nigbati nwọn nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, lati ijọba kan de ọdọ awọn enia miran;

14 On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni iwọsi: Nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn;

15 Pe, Ẹ máṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi ki ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi,

16 Pẹlupẹlu o pè ìyan wá si ilẹ na: o ṣẹ́ gbogbo ọpá onjẹ.

17 O rán ọkunrin kan lọ siwaju wọn; ani Josefu ti a tà li ẹrú:

18 Ẹsẹ ẹniti nwọn fi ṣẹkẹṣẹkẹ pa lara: a dè e ninu irin:

19 Titi igba ti ọ̀rọ rẹ̀ de: ọ̀rọ Oluwa dan a wò.

20 Ọba ranṣẹ, nwọn si tú u silẹ; ani ijoye awọn enia, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ.

21 O fi jẹ oluwa ile rẹ̀, ati ijoye gbogbo ini rẹ̀.

22 Lati ma ṣe akoso awọn ọmọ-alade rẹ̀ nipa ifẹ rẹ̀; ati lati ma kọ́ awọn igbimọ rẹ̀ li ọgbọ́n.

23 Israeli si wá si Egipti pẹlu; Jakobu si ṣe atipo ni ilẹ Hamu.

24 O si mu awọn enia rẹ̀ bi si i pipọ̀-pipọ̀; o si mu wọn lagbara jù awọn ọta wọn lọ.

25 O yi wọn li aiya pada lati korira awọn enia rẹ̀, lati ṣe arekereke si awọn iranṣẹ rẹ̀.

26 O rán Mose iranṣẹ rẹ̀; ati Aaroni, ẹniti o ti yàn.

27 Nwọn fi ọ̀rọ àmi rẹ̀ hán ninu wọn, ati iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu.

28 O rán òkunkun, o si mu u ṣú; nwọn kò si ṣaigbọran si ọ̀rọ rẹ̀.

29 O sọ omi wọn di ẹ̀jẹ, o si pa ẹja wọn.

30 Ilẹ wọn mu ọ̀pọlọ jade wá li ọ̀pọlọpọ, ni iyẹwu awọn ọba wọn.

31 O sọ̀rọ, oniruru eṣinṣin si de, ati ina-aṣọ ni gbogbo agbegbe wọn.

32 O fi yinyin fun wọn fun òjo, ati ọwọ iná ni ilẹ wọn.

33 O si lu àjara wọn, ati igi ọ̀pọtọ wọn; o si dá igi àgbegbe wọn.

34 O sọ̀rọ, eṣú si de ati kokoro li ainiye.

35 Nwọn si jẹ gbogbo ewebẹ ilẹ wọn, nwọn si jẹ eso ilẹ wọn run.

36 O kọlu gbogbo akọbi pẹlu ni ilẹ wọn, ãyo gbogbo ipa wọn.

37 O si mu wọn jade, ti awọn ti fadaka ati wura: kò si si alailera kan ninu ẹ̀ya rẹ̀.

38 Inu Egipti dùn nigbati nwọn lọ: nitoriti ẹ̀ru wọn bà wọn.

39 O nà awọsanma kan fun ibori; ati iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru.

40 Nwọn bère o si mu ẹiyẹ aparo wá, o si fi onjẹ ọrun tẹ wọn lọrun.

41 O là apata, omi si tú jade; odò nṣan nibi gbigbẹ.

42 Nitoriti o ranti ileri rẹ̀ mimọ́, ati Abrahamu iranṣẹ rẹ̀.

43 O si fi ayọ̀ mu awọn enia rẹ̀ jade, ati awọn ayanfẹ rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀:

44 O si fi ilẹ awọn keferi fun wọn: nwọn si jogun ère iṣẹ awọn enia na.

45 Ki nwọn ki o le ma kiye si aṣẹ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma pa ofin rẹ̀ mọ́. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.