1 IWỌ o ti gbagbe mi pẹ to, Oluwa, lailai? iwọ o ti pa oju rẹ mọ́ pẹ to kuro lara mi?
2 Emi o ti ma gbìmọ li ọkàn mi pẹ to? ti emi o ma ni ibinujẹ li ọkàn mi lojojumọ? ọta mi yio ti gberaga sori mi pẹ to?
3 Rò o, ki o si gbohùn mi, Oluwa Ọlọrun mi: mu oju mi mọlẹ, ki emi ki o má ba sùn orun ikú.
4 Ki ọta mi ki o má ba wipe, emi ti ṣẹgun rẹ̀; awọn ti nyọ mi lẹnu a si ma yọ̀, nigbati a ba ṣi mi nipò.
5 Ṣugbọn emi o gbẹkẹle ãnu rẹ; ọkàn mi yio yọ̀ ni igbala rẹ.
6 Emi o ma kọrin si Oluwa, nitoriti o ṣe fun mi li ọ̀pọlọpọ.