O. Daf 42 YCE

IWE KEJI

Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú

1 BI agbọnrin iti ma mi hẹlẹ si ipadò omi, Ọlọrun, bẹ̃li ọkàn mi nmi hẹlẹ si ọ.

2 Ongbẹ Ọlọrun ngbẹ ọkàn mi, ti Ọlọrun alãye: nigbawo li emi o wá, ti emi o si yọju niwaju Ọlọrun.

3 Omije mi li onjẹ mi li ọsan ati li oru, nigbati nwọn nwi fun mi nigbagbogbo pe, Ọlọrun rẹ dà?

4 Nigbati mo ba ranti nkan wọnyi, emi tú ọkàn mi jade ninu mi: emi ti ba ọ̀pọ ijọ enia lọ, emi ba wọn lọ si ile Ọlọrun, pẹlu ohùn ayọ̀ on iyìn, pẹlu ọ̀pọ enia ti npa ọjọ mimọ́ mọ́.

5 Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun: nitori emi o sa ma yìn i sibẹ fun iranlọwọ oju rẹ̀.

6 Ọlọrun mi, ori ọkàn mi tẹ̀ ba ninu mi: nitorina li emi o ṣe ranti rẹ lati ilẹ Jordani wá, ati lati Hermoni, lati òke Misari wá.

7 Ibu omi npè ibu omi nipa hihó ṣiṣan-omi rẹ: gbogbo riru omi ati bibì omi rẹ bò mi mọlẹ.

8 Ṣugbọn Oluwa yio paṣẹ iṣeun-ifẹ rẹ̀ nigba ọ̀san, ati li oru orin rẹ̀ yio wà pẹlu mi, ati adura mi si Ọlọrun ẹmi mi.

9 Emi o wi fun Ọlọrun, apata mi pe, Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe mi? ẽṣe ti emi fi nrìn ni ìgbawẹ nitori inilara ọta nì.

10 Bi ẹnipe idà ninu egungun mi li ẹ̀gan ti awọn ọta mi ngàn mi; nigbati nwọn nwi fun mi lojojumọ pe, Ọlọrun rẹ dà?

11 Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun; nitori emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi ati Ọlọrun mi.