1 ẼṢE ti awọn orilẹ-ède fi nbinu fùfu, ati ti awọn enia ngbero ohun asan?
2 Awọn ọba aiye kẹsẹ jọ, ati awọn ijoye ngbimọ pọ̀ si Oluwa ati si Ẹni-ororo rẹ̀ pe,
3 Ẹ jẹ ki a fa ìde wọn já, ki a si mu okùn wọn kuro li ọdọ wa.
4 Ẹniti o joko li ọrun yio rẹrin: Oluwa yio yọ ṣùti si wọn.
5 Nigbana ni yio sọ̀rọ si wọn ni ibinu rẹ̀, yio si yọ wọn lẹnu ninu ibinujẹ rẹ̀ kikan.
6 Ṣugbọn mo ti fi Ọba mi jẹ lori Sioni, òke mimọ́ mi.
7 Emi o si rohin ipinnu Oluwa: O ti wi fun mi pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bi ọ.
8 Bère lọwọ mi, emi o si fi awọn orilẹ-ède fun ọ ni ini rẹ, ati iha opin ilẹ li ọrọ̀-ilẹ rẹ.
9 Ọpá irin ni iwọ o fi fọ́ wọn; iwọ o si rún wọn womuwomu, bi ohun èlo amọ̀.
10 Njẹ nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n, ẹnyin ọba: ki a si kọ́ nyin, ẹnyin onidajọ aiye.
11 Ẹ fi ìbẹru sìn Oluwa, ẹ si ma yọ̀ ti ẹnyin ti iwarìri.
12 Fi ẹnu kò Ọmọ na lẹnu, ki o máṣe binu, ẹnyin a si ṣegbe li ọ̀na na, bi inu rẹ̀ ba ru diẹ kiun. Ibukún ni fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.