O. Daf 33 YCE

Orin Ìyìn

1 ẸMA yọ̀ niti Oluwa, ẹnyin olododo: nitoriti iyìn yẹ fun ẹni-diduro-ṣinṣin.

2 Ẹ ma fi duru yìn Oluwa: ẹ ma fi ohun-elo olokùn mẹwa kọrin si i.

3 Ẹ kọ orin titun si i: ẹ ma fi ọgbọngbọn lù ohun ọnà orin pẹlu ariwo.

4 Nitori ti ọ̀rọ Oluwa tọ́: ati gbogbo iṣẹ rẹ̀ li a nṣe ninu otitọ.

5 O fẹ otitọ ati idajọ: ilẹ aiye kún fun ãnu Oluwa.

6 Nipa ọ̀rọ Oluwa li a da awọn ọrun, ati gbogbo ogun wọn nipa ẽmí ẹnu rẹ̀.

7 O gbá awọn omi okun jọ bi ẹnipe òkiti kan: o tò ibu jọ ni ile iṣura.

8 Ki gbogbo aiye ki o bẹ̀ru Oluwa: ki gbogbo araiye ki o ma wà ninu ẹ̀ru rẹ̀.

9 Nitori ti o sọ̀rọ, o si ti ṣẹ; o paṣẹ, o si duro ṣinṣin.

10 Oluwa mu ìmọ awọn orilẹ-ède di asan: o mu arekereke awọn enia ṣaki.

11 Imọ Oluwa duro lailai, ìro inu rẹ̀ lati irandiran.

12 Ibukún ni fun orilẹ-ède na, Ọlọrun ẹniti Oluwa iṣe; ati awọn enia na ti o ti yàn ṣe ini rẹ̀.

13 Oluwa wò lati ọrun wá, o ri gbogbo ọmọ enia.

14 Lati ibujoko rẹ̀ o wò gbogbo araiye.

15 O ṣe aiya wọn bakanna; o kiyesi gbogbo iṣẹ wọn.

16 Kò si ọba kan ti a ti ọwọ ọ̀pọ ogun gba silẹ: kò si alagbara kan ti a fi agbara pupọ̀ gba silẹ.

17 Ohun asan li ẹṣin fun igbala: bẹ̃ni kì yio fi agbara nla rẹ̀ gbàni silẹ.

18 Kiye si i, oju Oluwa mbẹ lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, lara awọn ti nreti ninu ãnu rẹ̀;

19 Lati gba ọkàn wọn la lọwọ ikú, ati lati pa wọn mọ́ lãye ni igba ìyan.

20 Ọkàn wa duro de Oluwa: on ni iranlọwọ wa ati asà wa.

21 Nitori ti ọkàn wa yio yọ̀ niti rẹ̀, nitori ti awa ti gbẹkẹle orukọ rẹ̀ mimọ́.

22 Ki ãnu rẹ, Oluwa, ki o wà lara wa, gẹgẹ bi awa ti nṣe ireti rẹ.