O. Daf 115 YCE

Ọlọrun Òdodo

1 KÌ iṣe fun wa, Oluwa, kì iṣe fun wa, bikoṣe orukọ rẹ li a fi ogo fun nitori ãnu rẹ, ati nitori otitọ rẹ.

2 Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà nisisiyi?

3 Ṣugbọn Ọlọrun wa mbẹ li ọrun: o nṣe ohun-kohun ti o wù u.

4 Fadaka ati wura li ere wọn, iṣẹ ọwọ enia.

5 Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ: nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò riran.

6 Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò gbọran: nwọn ni imu, ṣugbọn nwọn kò gbõrun.

7 Nwọn li ọwọ, ṣugbọn nwọn kò lò o: nwọn li ẹsẹ, ṣugbọn nwọn kò rìn: bẹ̃ni nwọn kò sọ̀rọ lati ọfun wọn jade.

8 Awọn ti nṣe wọn dabi wọn; bẹ̃li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn.

9 Israeli, iwọ gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.

10 Ara-ile Aaroni, gbẹkẹle Oluwa, on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.

11 Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.

12 Oluwa ti nṣe iranti wa: yio bùsi i fun wa: yio bùsi i fun ara-ile Israeli; yio bùsi i fun ara-ile Aaroni.

13 Yio bùsi i fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ati ewe ati àgba.

14 Oluwa yio mu nyin bisi i siwaju ati siwaju, ẹnyin ati awọn ọmọ nyin.

15 Ẹnyin li ẹni-ibukún Oluwa, ti o da ọrun on aiye.

16 Ọrun ani ọrun ni ti Oluwa; ṣugbọn aiye li o fi fun awọn ọmọ enia.

17 Okú kò yìn Oluwa, ati gbogbo awọn ti o sọkalẹ lọ sinu idakẹ.

18 Ṣugbọn awa o ma fi ibukún fun Oluwa, lati igba yi lọ ati si i lailai. Ẹ yìn Oluwa.