O. Daf 106 YCE

Oore OLUWA fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa! Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun: nitoriti ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

2 Tali o le sọ̀rọ iṣẹ agbara Oluwa? tali o le fi gbogbo iyìn rẹ̀ hàn?

3 Ibukún ni fun awọn ti npa idajọ mọ́, ati ẹniti nṣe ododo ni igbagbogbo.

4 Oluwa, fi oju-rere ti iwọ ni si awọn enia rẹ ṣe iranti mi: fi igbala rẹ bẹ̀ mi wò.

5 Ki emi ki o le ri ire awọn ayanfẹ rẹ, ki emi ki o le yọ̀ ninu ayọ̀ orilẹ-ède rẹ, ki emi ki o le ma ṣogo pẹlu awọn enia ilẹ-ini rẹ.

6 Awa ti ṣẹ̀ pẹlu awọn baba wa, awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe buburu.

7 Iṣẹ iyanu rẹ kò yé awọn baba wa ni Egipti; nwọn kò ranti ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ; ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si ọ nibi okun, ani nibi Okun pupa.

8 Ṣugbọn o gbà wọn là nitori orukọ rẹ̀, ki o le mu agbara rẹ̀ nla di mimọ̀.

9 O ba Okun pupa wi pẹlu, o si gbẹ: bẹ̃li o sìn wọn là ibu ja bi aginju.

10 O si gbà wọn là li ọwọ ẹniti o korira wọn, o si rà wọn pada li ọwọ ọta nì.

11 Omi si bò awọn ọta wọn: ẹnikan wọn kò si kù.

12 Nigbana ni nwọn gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́: nwọn si kọrin iyìn rẹ̀.

13 Nwọn kò pẹ igbagbe iṣẹ rẹ̀: nwọn kò si duro de imọ̀ rẹ̀.

14 Nwọn si ṣe ifẹkufẹ li aginju, nwọn si dan Ọlọrun wò ninu aṣálẹ̀.

15 O si fi ifẹ wọn fun wọn; ṣugbọn o rán rirù si ọkàn wọn.

16 Nwọn ṣe ilara Mose pẹlu ni ibudo, ati Aaroni, ẹni-mimọ́ Oluwa.

17 Ilẹ là, o si gbé Datani mì, o si bò ẹgbẹ́ Abiramu mọlẹ.

18 Iná si ràn li ẹgbẹ́ wọn; ọwọ́ iná na jó awọn enia buburu.

19 Nwọn ṣe ẹgbọrọ malu ni Horebu, nwọn si foribalẹ fun ere didà.

20 Bayi ni nwọn pa ogo wọn dà si àworan malu ti njẹ koriko.

21 Nwọn gbagbe Ọlọrun, Olugbala wọn, ti o ti ṣe ohun nla ni ilẹ Egipti.

22 Iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu, ati ohun ẹ̀ru lẹba Okun pupa.

23 Nitorina li o ṣe wipe, on o run wọn, iba máṣe pe Mose, ayanfẹ rẹ̀, duro niwaju rẹ̀ li oju-ẹya na, lati yi ibinu rẹ̀ pada, ki o má ba run wọn.

24 Nitõtọ, nwọn kò kà ilẹ didara nì si, nwọn kò gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́:

25 Ṣugbọn nwọn nkùn ninu agọ wọn, nwọn kò si feti si ohùn Oluwa.

26 Nitorina li o ṣe gbé ọwọ rẹ̀ soke si wọn, lati bì wọn ṣubu li aginju:

27 Lati bì iru-ọmọ wọn ṣubu pẹlu lãrin awọn orilẹ-ède, ati lati fún wọn ka kiri ni ilẹ wọnni.

28 Nwọn da ara wọn pọ̀ pẹlu mọ Baali-Peoru, nwọn si njẹ ẹbọ okú.

29 Bayi ni nwọn fi iṣẹ wọn mu u binu: àrun nla si fó si arin wọn.

30 Nigbana ni Finehasi dide duro, o si ṣe idajọ: bẹ̃li àrun nla na si dá.

31 A si kà eyi na si fun u li ododo lati irandiran titi lai.

32 Nwọn bi i ninu pẹlu nibi omi Ijà, bẹ̃li o buru fun Mose nitori wọn:

33 Nitori ti nwọn mu ẹmi rẹ̀ binu, bẹ̃li o fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ aiyẹ.

34 Nwọn kò run awọn orilẹ-ède na, niti ẹniti Oluwa paṣẹ fun wọn:

35 Ṣugbọn nwọn da ara wọn pọ̀ mọ́ awọn keferi, nwọn si kọ́ iṣẹ wọn.

36 Nwọn si sìn ere wọn: ti o di ikẹkun fun wọn.

37 Nitõtọ nwọn fi ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn rubọ si oriṣa.

38 Nwọn si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ, ani ẹ̀jẹ awọn ọmọkunrin wọn ati ti awọn ọmọbinrin wọn, ti nwọn fi rubọ si ere Kenaani: ilẹ na si di aimọ́ fun ẹ̀jẹ.

39 Nwọn si fi iṣẹ ara wọn sọ ara wọn di alaimọ́, nwọn si ṣe panṣaga lọ pẹlu iṣẹ wọn.

40 Nitorina ni ibinu Oluwa ṣe ràn si awọn enia rẹ̀, o si korira awọn enia ini rẹ̀.

41 O si fi wọn le awọn keferi lọwọ; awọn ti o korira wọn si ṣe olori wọn.

42 Awọn ọta wọn si ni wọn lara, nwọn si mu wọn sìn labẹ ọwọ wọn.

43 Igba pupọ li o gbà wọn; sibẹ nwọn fi ìmọ wọn mu u binu, a si rẹ̀ wọn silẹ nitori ẹ̀ṣẹ wọn.

44 Ṣugbọn ninu ipọnju o kiyesi wọn, nigbati o gbọ́ ẹkún wọn.

45 O si ranti majẹmu rẹ̀ fun wọn, o si yi ọkàn pada gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀.

46 O si mu wọn ri ãnu loju gbogbo awọn ti o kó wọn ni igbekun.

47 Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa, ki o si ṣa wa jọ kuro lãrin awọn keferi, lati ma fi ọpẹ fun orukọ mimọ́ rẹ, ati lati ma ṣogo ninu iyìn rẹ.

48 Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lati aiyeraiye: ki gbogbo enia ki o si ma wipe, Amin. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.