1 OLUWA ni mo gbẹkẹ mi le: ẹ ha ti ṣe wi fun ọkàn mi pe, sá bi ẹiyẹ lọ si òke nyin?
2 Sa kiyesi i, awọn enia buburu ti fà ọrun wọn le, nwọn ti fi ọfa sùn li oju ọṣán, ki nwọn ki o le ta a li òkunkun si ọlọkàn diduro.
3 Bi ipilẹ ba bajẹ, kili olododo yio ṣe?
4 Oluwa mbẹ ninu tempili mimọ́ rẹ̀, itẹ́ Oluwa mbẹ li ọrun: oju rẹ̀ nwò, ipenpeju rẹ̀ ndán awọn ọmọ enia wò.
5 Oluwa ndán olododo wò: ṣugbọn enia buburu ati ẹniti nfẹ ìwa-agbara, ọkàn rẹ̀ korira.
6 Lori enia buburu ni yio rọjo, ẹyín gbigbona ati imi-ọjọ ati iji gbigbona: eyi ni ipin ago wọn.
7 Nitori olododo li Oluwa, o fẹ ododo; awọn ẹniti o duro-ṣinṣin yio ri oju rẹ̀.