O. Daf 103 YCE

Ìfẹ́ Ọlọrun

1 FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, ati gbogbo ohun ti o wà ninu mi, fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́.

2 Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, má si ṣe gbagbe gbogbo ore rẹ̀:

3 Ẹniti o dari gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ jì; ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ,

4 Ẹniti o ra ẹmi rẹ kuro ninu iparun; ẹniti o fi iṣeun-ifẹ ati iyọ́nu de ọ li ade:

5 Ẹniti o fi ohun didara tẹ́ ọ lọrun: bẹ̃ni igba ewe rẹ di ọtun bi ti idì.

6 Oluwa ṣe ododo ati idajọ fun gbogbo awọn ti a nilara.

7 O fi ọ̀na rẹ̀ hàn fun Mose, iṣe rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli.

8 Oluwa li alãnu ati olõre, o lọra ati binu, o si pọ̀ li ãnu.

9 On kì ibaniwi nigbagbogbo: bẹ̃ni kì ipa ibinu rẹ̀ mọ́ lailai.

10 On kì iṣe si wa gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ wa; bẹ̃ni kì isan a fun wa gẹgẹ bi aiṣedede wa.

11 Nitori pe, bi ọrun ti ga si ilẹ, bẹ̃li ãnu rẹ̀ tobi si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.

12 Bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun, bẹ̃li o mu irekọja wa jina kuro lọdọ wa.

13 Bi baba ti iṣe iyọ́nu si awọn ọmọ, bẹ̃li Oluwa nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.

14 Nitori ti o mọ̀ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wa.

15 Bi o ṣe ti enia ni, ọjọ rẹ̀ dabi koriko: bi itana eweko igbẹ bẹ̃li o gbilẹ.

16 Nitori ti afẹfẹ fẹ kọja lọ lori rẹ̀, kò sì si mọ́; ibujoko rẹ̀ kò mọ̀ ọ mọ́.

17 Ṣugbọn ãnu Oluwa lati aiyeraiye ni lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, ati ododo rẹ̀ lati ọmọ de ọmọ:

18 Si awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ mọ́, ati si awọn ti o ranti ofin rẹ̀ lati ṣe wọn.

19 Oluwa ti pèse itẹ́ rẹ̀ ninu ọrun; ijọba rẹ̀ li o si bori ohun gbogbo;

20 Ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin angeli rẹ̀, ti o pọ̀ ni ipa ti nṣe ofin rẹ̀, ti nfi eti si ohùn ọ̀rọ rẹ̀.

21 Ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀ gbogbo; ẹnyin iranṣẹ rẹ̀, ti nṣe ifẹ rẹ̀.

22 Ẹ fi ibukún fun Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ̀ ni ibi gbogbo ijọba rẹ̀: fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi.