1 NIGBATI Israeli jade kuro ni Egipti, ti ara-ile Jakobu kuro ninu àjeji ède enia;
2 Juda di ibi mimọ́ rẹ̀, Israeli di ijọba rẹ̀.
3 Okun ri i, o si sá: Jordani pada sẹhin.
4 Awọn òke nla nfò bi àgbo, ati awọn òke kekèke bi ọdọ-agutan.
5 Kili o ṣe ọ, iwọ okun, ti iwọ fi sá? iwọ Jordani ti iwọ fi pada sẹhin?
6 Ẹnyin òke nla, ti ẹ fi nfò bi àgbo; ati ẹnyin òke kekèke bi ọdọ-agutan?
7 Warìri, iwọ ilẹ, niwaju Oluwa, niwaju Ọlọrun Jakobu.
8 Ẹniti o sọ apata di adagun omi, ati okuta-ibọn di orisun omi.