O. Daf 44 YCE

Adura Ààbò

1 ỌLỌRUN, awa ti fi eti wa gbọ́, awọn baba wa si ti sọ fun wa ni iṣẹ́ nla ti iwọ ṣe li ọjọ wọn, ni igbà àtijọ́.

2 Bi iwọ ti fi ọwọ rẹ lé awọn keferi jade, ti iwọ si gbin wọn: bi iwọ ti fõró awọn enia na, ti iwọ si mu wọn gbilẹ.

3 Nitoriti nwọn kò ni ilẹ na nipa idà ara wọn, bẹ̃ni kì iṣe apá wọn li o gbà wọn; bikoṣe ọwọ ọtún rẹ ati apá rẹ, ati imọlẹ oju rẹ, nitoriti iwọ ni ifẹ rere si wọn.

4 Iwọ li Ọba mi, Ọlọrun: paṣẹ igbala fun Jakobu.

5 Nipasẹ̀ rẹ li awa o bì awọn ọta wa ṣubu: nipasẹ orukọ rẹ li awa o tẹ̀ awọn ti o dide si wa mọlẹ.

6 Nitoriti emi kì yio gbẹkẹle ọrun mi, bẹ̃ni idà mi kì yio gbà mi.

7 Ṣugbọn iwọ li o ti gbà wa lọwọ awọn ọta wa, iwọ si ti dojutì awọn ti o korira wa.

8 Niti Ọlọrun li awa nkọrin iyìn li ọjọ gbogbo, awa si nyìn orukọ rẹ lailai.

9 Ṣugbọn iwọ ti ṣa wa tì, iwọ si ti dojutì wa: iwọ kò si ba ogun wa jade lọ.

10 Iwọ mu wa pẹhinda fun ọta wa: ati awọn ti o korira wa nṣe ikogun fun ara wọn.

11 Iwọ ti fi wa fun jijẹ bi ẹran agutan; iwọ si ti tú wa ka ninu awọn keferi.

12 Iwọ ti tà awọn enia rẹ li asan, iwọ kò si fi iye-owo wọn sọ ọrọ̀ rẹ di pupọ.

13 Iwọ sọ wa di ẹ̀gan si awọn aladugbo wa, ẹlẹya ati iyọṣutì-si, si awọn ti o yi ni ka.

14 Iwọ sọ wa di ẹni-owe ninu awọn orilẹ-ède, ati imirisi ninu awọn enia.

15 Idamu mi mbẹ niwaju mi nigbagbogbo, itiju mi si bò mi mọlẹ.

16 Nitori ohùn ẹniti ngàn, ti o si nsọ̀rọ buburu; nitori ipa ti ọta olugbẹsan nì.

17 Gbogbo wọnyi li o de si wa; ṣugbọn awa kò gbagbe rẹ, bẹ̃li awa kò ṣe eke si majẹmu rẹ.

18 Aiya wa kò pada sẹhin, bẹ̃ni ìrin wa kò yà kuro ni ipa tirẹ;

19 Bi iwọ tilẹ ti fọ́ wa bajẹ ni ibi awọn ikõkò, ti iwọ si fi ojiji ikú bò wa mọlẹ.

20 Bi o ba ṣepe awa gbagbe orukọ Ọlọrun wa, tabi bi awa ba nà ọwọ wa si ọlọrun ajeji;

21 Njẹ Ọlọrun ki yio ri idi rẹ̀? nitori o mọ̀ ohun ìkọkọ aiya.

22 Nitõtọ, nitori rẹ li a ṣe npa wa kú ni gbogbo ọjọ; a nkà wa si bi agutan fun pipa.

23 Ji! ẽṣe ti iwọ nsùn, Oluwa? dide, máṣe ṣa wa tì kuro lailai.

24 Ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́, ti iwọ si fi gbagbe ipọnju wa ati inira wa?

25 Nitoriti a tẹri ọkàn wa ba sinu ekuru: inu wa dì mọ erupẹ ilẹ.

26 Dide fun iranlọwọ wa, ki o si rà wa pada nitori ãnu rẹ.