1 ỌLỌRUN duro ninu ijọ awọn alagbara; o nṣe idajọ ninu awọn ọlọrun.
2 Ẹnyin o ti ṣe idajọ aiṣõtọ pẹ to, ti ẹ o si ma ṣe ojuṣaju awọn enia buburu?
3 Ṣe idajọ talaka, ati ti alaini-baba: ṣe otitọ si awọn olupọnju ati alaini.
4 Gbà talaka ati alaini: yọ wọn li ọwọ awọn enia buburu.
5 Nwọn kò mọ̀, bẹ̃ni nwọn kò fẹ ki oye ki o ye wọn; nwọn nrìn li òkunkun; gbogbo ipilẹ aiye yẹ̀ ni ipò wọn.
6 Emi ti wipe, ọlọrun li ẹnyin; awọn ọmọ Ọga-ogo si ni gbogbo nyin.
7 Ṣugbọn ẹnyin o kú bi enia, ẹnyin o si ṣubu bi ọkan ninu awọn ọmọ-alade.
8 Ọlọrun, dide, ṣe idajọ aiye: nitori iwọ ni yio ni orilẹ-ède gbogbo.