1 Ẹ FI fun Oluwa, ẹnyin ọmọ awọn alagbara, ẹ fi ogo ati agbara fun Oluwa.
2 Ẹ fi ogo fun Oluwa, ti o yẹ fun orukọ rẹ̀; ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́.
3 Ohùn Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀: Ọlọrun ogo nsán ãrá: Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀.
4 Ohùn Oluwa li agbara; ohùn Oluwa ni ọlánla.
5 Ohùn Oluwa nfà igi kedari ya; lõtọ, Oluwa nfà igi kedari Lebanoni ya.
6 O mu wọn fò pẹlu bi ọmọ-malu; Lebanoni on Sirioni bi ọmọ agbanrere.
7 Ohùn Oluwa nyà ọwọ iná,
8 Ohùn Oluwa nmì aginju; Oluwa nmì aginju Kadeṣi.
9 Ohùn Oluwa li o nmu abo agbọnrin bi, o si fi igbo didi hàn: ati ninu tempili rẹ̀ li olukuluku nsọ̀rọ ogo rẹ̀.
10 Oluwa joko lori iṣan-omi; nitõtọ, Oluwa joko bi Ọba lailai.
11 Oluwa yio fi agbara fun awọn enia rẹ̀; Oluwa yio fi alafia busi i fun awọn enia rẹ̀.