O. Daf 136 YCE

Orin Ọpẹ́

1 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

2 Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun awọn ọlọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

3 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn oluwa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

4 Fun on nikan ti nṣe iṣẹ iyanu nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

5 Fun ẹniti o fi ọgbọ́n da ọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

6 Fun ẹniti o tẹ́ ilẹ lori omi: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

7 Fun ẹniti o dá awọn imọlẹ nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

8 Õrùn lati jọba ọsan: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:

9 Oṣupa ati irawọ lati jọba oru: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

10 Fun ẹniti o kọlù Egipti lara awọn akọbi wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

11 O si mu Israeli jade kuro lãrin wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:

12 Pẹlu ọwọ agbara, ati apa ninà: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

13 Fun ẹniti o pin Okun pupa ni ìya: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:

14 O si mu Israeli kọja lọ larin rẹ̀: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

15 Ṣugbọn o bi Farao ati ogun rẹ̀ ṣubu ninu Okun pupa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

16 Fun ẹniti o sin awọn enia rẹ̀ la aginju ja: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

17 Fun ẹniti o kọlù awọn ọba nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

18 O si pa awọn ọba olokiki: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

19 Sihoni, ọba awọn ara Amori: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

20 Ati Ogu, ọba Baṣani: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

21 O si fi ilẹ wọn funni ni ini, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

22 Ini fun Israeli, iranṣẹ rẹ̀; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

23 Ẹniti o ranti wa ni ìwa irẹlẹ wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

24 O si dá wa ni ìde lọwọ awọn ọta wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

25 Ẹniti o nfi onjẹ fun ẹda gbogbo: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai;

26 Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun ọrun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.