1 ṢÃNU fun mi: Ọlọrun, ṣãnu fun mi: nitoriti ọkàn mi gbẹkẹle ọ: lõtọ, li ojiji iyẹ-apa rẹ li emi o fi ṣe àbo mi, titi wahala wọnyi yio fi rekọja.
2 Emi o kigbe pe Ọlọrun Ọga-ogo; si Ọlọrun ti o ṣe ohun gbogbo fun mi.
3 On o ranṣẹ lati ọrun wá, yio si gbà mi bi ẹniti nfẹ gbe mi mì tilẹ nkẹgàn mi. Ọlọrun yio rán ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ jade.
4 Ọkàn mi wà lãrin awọn kiniun: emi tilẹ dubulẹ lãrin awọn ti o gbiná, eyinì ni awọn ọmọ enia, ehín ẹniti iṣe ọ̀kọ ati ọfa, ati ahọn wọn, idà mimú.
5 Gbigbega ni ọ, Ọlọrun, jù ọrun lọ; ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ.
6 Nwọn ti ta àwọn silẹ fun ẹsẹ mi: nwọn tẹ ori ọkàn mi ba: nwọn ti wà iho silẹ niwaju mi, li ãrin eyina li awọn tikarawọn jìn si.
7 Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun, ọkàn mi ti mura: emi o kọrin, emi o si ma kọrin iyìn.
8 Jí, iwọ ogo mi; jí, ohun-èlo orin ati duru: emi tikarami yio si jí ni kutukutu.
9 Emi o ma yìn ọ, Oluwa lãrin awọn enia: emi o si ma kọrin si ọ lãrin awọn orilẹ-ède.
10 Nitoriti ãnu rẹ pọ̀ de ọrun, ati otitọ rẹ de awọsanma.
11 Gbigbega ni ọ, Ọlọrun, jù awọn ọrun lọ ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ.