1 ỌLỌRUN, fi idajọ rẹ fun ọba, ati ododo rẹ fun ọmọ ọba.
2 On o ma fi ododo ṣe idajọ awọn enia rẹ, yio si ma fi ẹtọ́ ṣe idajọ awọn talaka rẹ.
3 Awọn òke nla yio ma mu alafia fun awọn enia wá, ati awọn òke kekeke nipa ododo.
4 On o ma ṣe idajọ awọn talaka enia, yio ma gbà awọn ọmọ awọn alaini, yio si fà aninilara ya pẹrẹ-pẹrẹ.
5 Nwọn o si ma bẹ̀ru rẹ, niwọ̀n bi õrùn ati oṣupa yio ti pẹ to, lati irandiran.
6 On o rọ̀ si ilẹ bi ojò si ori koriko itẹ̀mọlẹ: bi ọwọ òjo ti o rin ilẹ.
7 Li ọjọ rẹ̀ li awọn olododo yio gbilẹ: ati ọ̀pọlopọ alafia niwọn bi òṣupa yio ti pẹ to.
8 On o si jọba lati okun de okun, ati lati odò nì de opin aiye.
9 Awọn ti o joko li aginju yio tẹriba fun u; awọn ọta rẹ̀ yio si lá erupẹ ilẹ.
10 Awọn ọba Tarṣiṣi, ati ti awọn erekuṣu yio mu ọrẹ wá: awọn ọba Ṣeba ati ti Seba yio mu ẹ̀bun wá.
11 Nitõtọ, gbogbo awọn ọba ni yio wolẹ niwaju rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma sìn i.
12 Nitori yio gbà alaini nigbati o ba nke: talaka pẹlu, ati ẹniti kò li oluranlọwọ.
13 On o da talaka ati alaini si, yio si gbà ọkàn awọn alaini là.
14 On o rà ọkàn wọn pada lọwọ ẹ̀tan ati ìwa-agbara: iyebiye si li ẹ̀jẹ wọn li oju rẹ̀.
15 On o si yè, on li a o si fi wura Ṣeba fun: a o si ma gbadura fun u nigbagbogbo: lojojumọ li a o si ma yìn i.
16 Ikúnwọ ọkà ni yio ma wà lori ilẹ, lori awọn òke nla li eso rẹ̀ yio ma mì bi Lebanoni: ati awọn ti inu ilu yio si ma gbà bi koriko ilẹ.
17 Orukọ rẹ̀ yio wà titi lai: orukọ rẹ̀ yio ma gbilẹ niwọn bi õrun yio ti pẹ to: nwọn o si ma bukún fun ara wọn nipaṣẹ rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma pè e li alabukúnfun.
18 Olubukún li Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun Israeli, ẹnikanṣoṣo ti nṣe ohun iyanu.
19 Olubukún li orukọ rẹ̀ ti o li ogo titi lai: ki gbogbo aiye ki o si kún fun ogo rẹ̀; Amin Amin.
20 Adura Dafidi ọmọ Jesse pari.