1 OLUWA, tani yio ma ṣe atipo ninu agọ rẹ? tani yio ma gbe inu òke mimọ́ rẹ?
2 Ẹniti o nrìn dede, ti nṣiṣẹ ododo, ti o si nsọ otitọ inu rẹ̀.
3 Ẹniti kò fi ahọn rẹ̀ sọ̀rọ ẹni lẹhin, ti kò si ṣe ibi si ẹnikeji rẹ̀, ti kò si gbà ọ̀rọ ẹ̀gan si ẹnikeji rẹ̀.
4 Li oju ẹniti enia-kenia di gigàn; ṣugbọn a ma bu ọla fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa. Ẹniti o bura si ibi ara rẹ̀, ti kò si yipada.
5 Ẹniti kò fi owo rẹ̀ gbà èle, ti kò si gbà owo ẹ̀bẹ si alaiṣẹ. Ẹniti o ba ṣe nkan wọnyi kì yio yẹsẹ lailai.